Àgbéyẹ̀wò Oríṣiríṣi Ijó nínú Ìṣeré Orin Kete àti Orin Agbè
Uma visão geral das várias danças em apresentações musicais de Kete e Agbe
Palavras-chave:
Àrokò, Ìṣeré, Ijó, Orin Kete, Orin AgbèResumo
ÀṢAMỌ̀
Ìjó jíjó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú oríṣiríṣi eré tí àwọn òṣèré ewì alohùn Yorùbá máa ń ṣe lásìkò ìṣeré wọn. Ìbéèrè tí ó jẹ wá lógún nínú àtúpalẹ̀ lámèétọ́ inú àpilẹ̀kọ yìí ni pé irú àwọn ijó wo ni ó wà nínú ìṣeré orin kete àti orin agbè, kí sì ni àrokò tí àwón eléré fi wọn pa? Nínú àgbéyẹ̀wò wa yìí a gbìyànjú láti ṣe ọ̀ríkínniwín àlàyé nípa àrokò tí àwọn òṣèré fi ijó pa nínú ìṣseré orin kete àti orin agbè tí a gbà láti oko ìwádìí. Tíọ́rì ìlò-àmì nínú ewì (semiotics of poetry), ti Michael Riffaterre (1978) àti tíọ́rì ìṣeré (performance theory), ti Richard Schechner (2004) ni a múlò fún ìtúpalẹ̀ détà wa. Láti Igbó-Ọrà, ní Ìbàràpá, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni a ti gba détà lórí orin kete, a sì gba détà lórí orin agbè láti Igbó-Ọrà kan náà pẹ̀lú Ilùà àti Ìmia ní Òkè-Ògùn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ìlànà agbàròkọ alálàyé àti ti àfiwéra ní a gùn lé láti ṣe àtúpalẹ̀ àwọn détà náà. Ìwádìí wa fi hàn pé lára àwọn ijó tó gbajúmọ̀, èyí tí ó máa ń jéyọ nínú àti orin kete, àti orin agbè ni ìlù/ agbè jíjá, ìdọ̀bálẹ̀/ ìyíkàá, fífi-èjìká-jó, olóbìírípobírí/ bírípo pẹ̀lú ijó àti ilù/ agbè lílù papọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Ijó yíyatan-pípatandé nìkan ni ìwádìí wa fi hàn pé ó máa ń jéyọ nínú orin kete ṣùgbọ́n tí kì í jẹyọ nínú orin agbè. Àwọn ijó tó máa ń jẹyọ nínú orin agbè ṣùgbọ́n tí kì í jẹyọ nínú orin kete sì ni fiwájú-jó-fẹ̀yìn-jó, yọpáyọsẹ̀/ ẹlẹ́yọ-ẹ̀yọ, fò-lálá àti mẹ́tamẹ́ta-ẹ̀là/ là-á-mẹ́ta. Àrokò ajẹmẹ́sìn òrìṣà Alárá-Igbó àti ìmọ̀-ọ́n-ṣe nínú ijó jíjó ni àrokò tí ijó pa nínú orin kete, ṣùgbọ́n àrokò ajẹmọ́-ìbágbépọ̀-láwùjọ àti ìmọ̀-ọ́n-ṣe nínú ijó papọ̀ mọ́ àfihàn agbára ni wọ́n fi ijó agbè pa nínú orin agbè. Àrokò ìṣewẹ́kú pẹ̀lú ìwọ́hùn orin náà jẹyọ nínú ìṣeré orin méjèèjì.
*****
A dança é uma das principais formas de dança que os poetas líricos iorubás realizam durante suas apresentações. A questão que nos interessa na análise deste artigo é quais tipos de danças são incluídos na performance de kete e agbê, e qual é a narrativa para a qual os artistas as utilizam? Nesta revisão, tentamos fornecer uma explicação abrangente da narrativa que os artistas usam para dançar na performance de kete e agbê que obtivemos da pesquisa. A semiótica da teoria da poesia, de Michael Riffaterre (1978), e a teoria da performance, de Richard Schechner (2004), foram usadas para nossa análise de dados. Dados sobre a música kete foram coletados em Igbó-Òra, em Ibarapá, estado de Oyo, e dados sobre a música agbé foram coletados no mesmo Igbó-Òra com Ilua e Ìmia em Òke-Ógùn, estado de Oyo. Métodos de análise descritiva e comparativa foram usados para analisar os dados. Nossa pesquisa mostrou que entre as danças populares que ocorrem tanto na música kete quanto na música agbé estão ìlû/abgé jija, ìdóbále/ìííkáá, fifi-éjúká-jo, olibiípobírí/birípo com dança e ilû/abgé lílu juntos. Nossa pesquisa mostrou que apenas a dança yiyatan-pípatandé ocorre na música kete, mas não na música agbé. As danças que são frequentemente encontradas na música abade, mas não na música kete, incluem fiwaku-jo-f'yin-jo, yopáyósọ/peẹ̀yó-é̀yó, fó-lálá e metaméta-é̀la/lá-á-méta. O tema da adoração à divindade igbo e o conhecimento da dança são os temas que a dança transmite na música kete, mas o tema da conexão social e o conhecimento da dança, juntamente com a demonstração de poder, são transmitidos na música abbe. O tema da morte e o som da canção são evidentes em ambas as apresentações musicais.
Downloads
Referências
Adélékè, D. A. (KND). Ìfáárà sí orin àpilẹ̀kọ Yorùbá. Ìbàdàn: Distance Learning Centre.
Àlàbá I. O. (1985). A Socio-Stylistic Analysis of Orin Agbè: A Multimodal Genre of Yorùbá Oral Poetry, àpilẹ̀kọ fún oyè Ph.D, Department of African Languages and Literatures, Faculty of Arts, University of Lagos.
Auslander, P. (2008). Theory for Performance Studies: A Student’s Guide. New York: Routledge.
Cobley, P. (2005). The Routledge Companion to Semiotics and Linguistics. London: Routledge.
Eco, U. (1976). A Theory of Semiotics. U.S.A: Indiana University Press.
Jakobson, R. (1960). Closing Statement: Linguistics and Poetics, nínú Style in Language, ed. ``Thomas A. Sebeok, M. I. T., Massaachusets, Cambridge, o. i. 350-449.
Kíaríbẹ̀ẹ́, L. A. (2022a). Social Status of Agbè and Kete: A Historical and Functional Yorùbá Oral Literary Perspectives, nínú Notion: Journal of Linguistics, Literature and Culture, vol. 4(2), o.i. 76-84.
___________ (2022b). Àgbéyẹ̀wò Pípe Àkíyèsí Àwùjọ sí Ìlera wọn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń Jẹyọ nínú Orin Ìbejì àti Orin Ẹgbẹ́, Yorùbá: Journal of Yorùbá Studies Association of Nigeria, Vol. 10. No. 2, o.i. 41-54.
__________ (2023). A comparative performance semiotics of Orin Kete and Orin Agbè Among the Ìbàràpá and Òkè-Ògùn people of Yorùbá, Nigeria, àpilẹ̀kọ fún òyè Ph.D, Department of Linguistics and African Languages, Univerisity of Ibadan.
Lotman, Y. M. (1990). The Universe of Mind: A Semiotic of Culture. Bloomington and Indianapolis: Indiana University Press.
Ògúndèjì, P. A. (1979). Ṣàkàrá Song in Ìṣẹmilé, àpilẹ̀kọ fún oyè B.A., Department of Linguistics and African Languages, University of Ìbàdàn, Ìbàdàn.
__________ (1988). A Semiotic Study of Duro Ladipọ’s Mythico-Historical Plays, àpilẹ̀kọ fún oyè Ph.D, Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan, Nigeria.
_________ (1991). Introduction to Yorùbá Oral Literature. Ibadan: University of Ibadan Centre for External Studies
________ 2000. Ritual as Theatre, Theatre as Ritual: The Nigeria Example. Ibadan: Ìbàdàn Culture Studies Group and Atlantic Books.
Òjó, M.A. (1978). Sákárà Muisic, àpilẹ̀kọ fún oyè M.A., Ẹka-ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ ẹ̀dé-èdè àti èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀, Yunifásitì Ìbàdàn.
Ọlátẹ́jú, M. O. A. (1998). A Syntactic Approach to Literary Discourse Analysis: The Yorùbá Example, àpilẹ̀kọ fún oyè Ph.D, Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan, Ibadan.
Ọ̀pádọ̀tun, Ọ. (2002). Okòó ewì alohùn. Ọ̀yọ́: Odumat Press & Publishers.
Owólabí, O. (1974). Orí Adé Kìí Sùnta. Lagos: Macmillan Nigeria Publishers Ltd.
Riffaterre, M. (1978). Semiotics of Poetry.Bloominngton àti London, Indiana University Press.
Schechner, R. (2004). Performance Theory (Revised and Expanded Edition). New York and London; Routledge.
Sonnentag, S. and Frese, M. 2002. Performance Concepts and Performance Theory, nínú Psychological Management of Individual Performance, Sonnentag, S. ed., o.i. 4-25.
Downloads
Publicado
Como Citar
Edição
Seção
Licença
Copyright (c) 2025 NJINGA e SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras (ISSN: 2764-1244)

Este trabalho está licenciado sob uma licença Creative Commons Attribution-NonCommercial-NoDerivatives 4.0 International License.
1.Autores mantêm os direitos autorais e concedem à revista o direito de primeira publicação, sendo o trabalho simultaneamente licenciado sob a Creative Commons Attribution License o que permite o compartilhamento do trabalho com reconhecimento da autoria do trabalho e publicação inicial nesta revista. A Revista usa a Licença CC BY que permite que outros distribuam, remixem, adaptem e criem a partir do seu trabalho, mesmo para fins comerciais, desde que lhe atribuam o devido crédito pela criação original. É a licença mais flexível de todas as licenças disponíveis. É recomendada para maximizar a disseminação e uso dos materiais licenciados.
2.Autores têm autorização para assumir contratos adicionais separadamente, para distribuição não exclusiva da versão do trabalho publicada nesta revista (ex.: publicar em repositório digital institucional ou como capítulo de livro), com reconhecimento de autoria e publicação inicial nesta revista.
3.Autores têm permissão e são estimulados a publicar e distribuir seu trabalho online (ex.: em repositórios institucionais ou na sua página pessoal, nas redes sociais) a qualquer ponto antes ou durante o processo editorial, já que isso pode gerar alterações produtivas, bem como aumentar o impacto e a citação do trabalho publicado (Trata-se da política de Acesso Livre).
