Àgbéyẹ̀wò Oríṣiríṣi Ijó nínú Ìṣeré Orin Kete àti Orin Agbè

Uma visão geral das várias danças em apresentações musicais de Kete e Agbe

Authors

  • Luqman Abísọ́lá KÍARÍBẸ̀Ẹ́ Ọ̀ṣun State University, Òṣogbo, Nigeria https://orcid.org/0000-0001-9894-8251
  • Philip Adédọ̀tun ÒGÚNDÈJÌ University of Ìbàdàn, Ìbàdàn

Keywords:

Àrokò, Ìṣeré, Ijó, Orin Kete, Orin Agbè

Abstract

ÀṢAMỌ̀ 

Ìjó jíjó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú oríṣiríṣi eré tí àwọn òṣèré ewì alohùn Yorùbá máa ń ṣe lásìkò ìṣeré wọn. Ìbéèrè tí ó jẹ wá lógún nínú àtúpalẹ̀ lámèétọ́ inú àpilẹ̀kọ yìí ni pé irú àwọn ijó wo ni ó wà nínú ìṣeré orin kete àti orin agbè, kí sì ni àrokò tí àwón eléré fi wọn pa? Nínú àgbéyẹ̀wò wa yìí a gbìyànjú láti ṣe ọ̀ríkínniwín àlàyé nípa àrokò tí àwọn òṣèré fi ijó pa nínú ìṣseré orin kete àti orin agbè tí a gbà láti oko ìwádìí. Tíọ́rì ìlò-àmì nínú ewì (semiotics of poetry), ti Michael Riffaterre (1978) àti tíọ́rì ìṣeré (performance theory), ti Richard Schechner (2004) ni a múlò fún ìtúpalẹ̀ détà wa. Láti  Igbó-Ọrà, ní Ìbàràpá, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni a ti gba détà lórí orin kete, a sì gba détà lórí orin agbè láti Igbó-Ọrà kan náà pẹ̀lú Ilùà àti Ìmia ní Òkè-Ògùn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ìlànà agbàròkọ alálàyé àti ti  àfiwéra ní a gùn lé láti ṣe àtúpalẹ̀ àwọn détà náà. Ìwádìí wa fi hàn pé lára àwọn ijó tó gbajúmọ̀, èyí tí ó máa ń jéyọ nínú àti orin kete, àti orin agbè ni ìlù/ agbè jíjá, ìdọ̀bálẹ̀/ ìyíkàá, fífi-èjìká-jó, olóbìírípobírí/ bírípo pẹ̀lú ijó àti ilù/ agbè lílù papọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Ijó yíyatan-pípatandé nìkan ni ìwádìí  wa fi hàn pé ó máa ń jéyọ nínú orin kete ṣùgbọ́n tí kì í jẹyọ nínú orin agbè. Àwọn ijó tó máa ń jẹyọ nínú orin agbè ṣùgbọ́n tí kì í jẹyọ nínú orin kete sì ni fiwájú-jó-fẹ̀yìn-jó, yọpáyọsẹ̀/ ẹlẹ́yọ-ẹ̀yọ, fò-lálá àti mẹ́tamẹ́ta-ẹ̀là/ là-á-mẹ́ta. Àrokò ajẹmẹ́sìn òrìṣà Alárá-Igbó àti ìmọ̀-ọ́n-ṣe nínú ijó jíjó ni àrokò tí ijó pa nínú orin kete, ṣùgbọ́n àrokò ajẹmọ́-ìbágbépọ̀-láwùjọ àti ìmọ̀-ọ́n-ṣe nínú ijó papọ̀ mọ́ àfihàn agbára ni wọ́n fi ijó agbè pa nínú orin agbè.  Àrokò ìṣewẹ́kú pẹ̀lú ìwọ́hùn orin náà jẹyọ  nínú ìṣeré orin méjèèjì.

*****

A dança é uma das principais formas de dança que os poetas líricos iorubás realizam durante suas apresentações. A questão que nos interessa na análise deste artigo é quais tipos de danças são incluídos na performance de kete e agbê, e qual é a narrativa para a qual os artistas as utilizam? Nesta revisão, tentamos fornecer uma explicação abrangente da narrativa que os artistas usam para dançar na performance de kete e agbê que obtivemos da pesquisa. A semiótica da teoria da poesia, de Michael Riffaterre (1978), e a teoria da performance, de Richard Schechner (2004), foram usadas para nossa análise de dados. Dados sobre a música kete foram coletados em Igbó-Òra, em Ibarapá, estado de Oyo, e dados sobre a música agbé foram coletados no mesmo Igbó-Òra com Ilua e Ìmia em Òke-Ógùn, estado de Oyo. Métodos de análise descritiva e comparativa foram usados para analisar os dados. Nossa pesquisa mostrou que entre as danças populares que ocorrem tanto na música kete quanto na música agbé estão ìlû/abgé jija, ìdóbále/ìííkáá, fifi-éjúká-jo, olibiípobírí/birípo com dança e ilû/abgé lílu juntos. Nossa pesquisa mostrou que apenas a dança yiyatan-pípatandé ocorre na música kete, mas não na música agbé. As danças que são frequentemente encontradas na música abade, mas não na música kete, incluem fiwaku-jo-f'yin-jo, yopáyósọ/peẹ̀yó-é̀yó, fó-lálá e metaméta-é̀la/lá-á-méta. O tema da adoração à divindade igbo e o conhecimento da dança são os temas que a dança transmite na música kete, mas o tema da conexão social e o conhecimento da dança, juntamente com a demonstração de poder, são transmitidos na música abbe. O tema da morte e o som da canção são evidentes em ambas as apresentações musicais.

Downloads

Download data is not yet available.

Author Biography

Philip Adédọ̀tun ÒGÚNDÈJÌ , University of Ìbàdàn, Ìbàdàn

Department of Linguistics and African Language, Faculty of Arts, University of Ìbàdàn, Ìbàdàn,

References

Adélékè, D. A. (KND). Ìfáárà sí orin àpilẹ̀kọ Yorùbá. Ìbàdàn: Distance Learning Centre.

Àlàbá I. O. (1985). A Socio-Stylistic Analysis of Orin Agbè: A Multimodal Genre of Yorùbá Oral Poetry, àpilẹ̀kọ fún oyè Ph.D, Department of African Languages and Literatures, Faculty of Arts, University of Lagos.

Auslander, P. (2008). Theory for Performance Studies: A Student’s Guide. New York: Routledge.

Cobley, P. (2005). The Routledge Companion to Semiotics and Linguistics. London: Routledge.

Eco, U. (1976). A Theory of Semiotics. U.S.A: Indiana University Press.

Jakobson, R. (1960). Closing Statement: Linguistics and Poetics, nínú Style in Language, ed. ``Thomas A. Sebeok, M. I. T., Massaachusets, Cambridge, o. i. 350-449.

Kíaríbẹ̀ẹ́, L. A. (2022a). Social Status of Agbè and Kete: A Historical and Functional Yorùbá Oral Literary Perspectives, nínú Notion: Journal of Linguistics, Literature and Culture, vol. 4(2), o.i. 76-84.

___________ (2022b). Àgbéyẹ̀wò Pípe Àkíyèsí Àwùjọ sí Ìlera wọn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń Jẹyọ nínú Orin Ìbejì àti Orin Ẹgbẹ́, Yorùbá: Journal of Yorùbá Studies Association of Nigeria, Vol. 10. No. 2, o.i. 41-54.

__________ (2023). A comparative performance semiotics of Orin Kete and Orin Agbè Among the Ìbàràpá and Òkè-Ògùn people of Yorùbá, Nigeria, àpilẹ̀kọ fún òyè Ph.D, Department of Linguistics and African Languages, Univerisity of Ibadan.

Lotman, Y. M. (1990). The Universe of Mind: A Semiotic of Culture. Bloomington and Indianapolis: Indiana University Press.

Ògúndèjì, P. A. (1979). Ṣàkàrá Song in Ìṣẹmilé, àpilẹ̀kọ fún oyè B.A., Department of Linguistics and African Languages, University of Ìbàdàn, Ìbàdàn.

__________ (1988). A Semiotic Study of Duro Ladipọ’s Mythico-Historical Plays, àpilẹ̀kọ fún oyè Ph.D, Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan, Nigeria.

_________ (1991). Introduction to Yorùbá Oral Literature. Ibadan: University of Ibadan Centre for External Studies

________ 2000. Ritual as Theatre, Theatre as Ritual: The Nigeria Example. Ibadan: Ìbàdàn Culture Studies Group and Atlantic Books.

Òjó, M.A. (1978). Sákárà Muisic, àpilẹ̀kọ fún oyè M.A., Ẹka-ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ ẹ̀dé-èdè àti èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀, Yunifásitì Ìbàdàn.

Ọlátẹ́jú, M. O. A. (1998). A Syntactic Approach to Literary Discourse Analysis: The Yorùbá Example, àpilẹ̀kọ fún oyè Ph.D, Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan, Ibadan.

Ọ̀pádọ̀tun, Ọ. (2002). Okòó ewì alohùn. Ọ̀yọ́: Odumat Press & Publishers.

Owólabí, O. (1974). Orí Adé Kìí Sùnta. Lagos: Macmillan Nigeria Publishers Ltd.

Riffaterre, M. (1978). Semiotics of Poetry.Bloominngton àti London, Indiana University Press.

Schechner, R. (2004). Performance Theory (Revised and Expanded Edition). New York and London; Routledge.

Sonnentag, S. and Frese, M. 2002. Performance Concepts and Performance Theory, nínú Psychological Management of Individual Performance, Sonnentag, S. ed., o.i. 4-25.

Published

06-08-2025

How to Cite

KÍARÍBẸ̀Ẹ́ L. A. . ., & ÒGÚNDÈJÌ , P. A. . (2025). Àgbéyẹ̀wò Oríṣiríṣi Ijó nínú Ìṣeré Orin Kete àti Orin Agbè: Uma visão geral das várias danças em apresentações musicais de Kete e Agbe. NJINGA&SEPÉ: evista nternacional e ulturas, Línguas fricanas rasileiras, 5(Especial I), 32–60. etrieved from https://revistas.unilab.edu.br/njingaesape/article/view/2323