Ìlò òwe akọni D.O. Fágúnwà nínú ìwé ìtàn àròsọ ògbójú ọdẹ nínú igbó irúnmọlẹ̀
O uso do provérbio "Akoni d.o. Fágúnwà" na história "Ogbogu Odey", na floresta da selva
Mots-clés :
Òwe, Fágúnwà, Ìtàn-Àròsọ, Ògbójú-Ọdẹ, Irúnmalẹ̀Résumé
Ohun tí iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí dá lé lórí ni àwọn òwe inú ìwé ìtàn àròsọ Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmalẹ̀ (Ògbójú, láti ìsisìyìí lọ) tí akọni òǹkọ̀wé Daniel Ọlọ́runfẹ́mi Fágúnwà kọ. Ohun tó sì jẹ wá lógún ni ṣíṣe àfihàn pàtàkì àti ìlò wọn gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ajẹmọ́ èdè, àṣà àti ọ̀nà ìgbàsọ̀tàn nínú ìwé Ògbójú. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀, ní àwùjọ Yorùbá àti ilẹ̀ Adúláwọ̀ lápapọ̀, òwe ni kókó nínú ìbáraẹnisọ̀rọ̀, ojú àmúwayé àti àmúlò fún ìsọ ajẹmọ́ ọgbọ́n, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìwà-ẹ̀tọ́ láàrin àwùjọ. Nínú Ògbójú, àwọn òwe wọ̀nyí jẹ́ ohun èlò pàtàkì tó mú kí ó jẹ́ gbajúgbajà òǹkọ̀wé ìtàn-àròsọ. Ìṣọwọ́lò àwọn òwe wọ̀nyí ló sì mú kí Fágúnwà di akọni òǹkọ̀wé Yorùbá láwùjọ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀. Tíọ́rì àmúlò fún ìtúpalẹ̀ iṣẹ́ yìí jẹ́ ti ọlọ́pọ̀ ìmọ̀. Àkọ́kọ́ ni tíọ́rì tó jẹ́ ẹ̀kọ́ nípa ìrísí, ìtumọ̀, orísun, ìpínsísọ̀rí, ìhun àti ìwúlò wọn. Èkejì ni tíọ́rì ajẹmọ́ àṣà alohùn tó níí ṣe pẹ̀lú àmúlò àwọn òwe nípa ìlànà àtẹnudẹ́nu dípò àkọsílẹ̀. Tíọ́rì kẹta ni èyí tó ń ṣàlàyé ohun gan-an tí òwe ń ṣe nínú ìsọ yàtọ̀ sí ìtumọ̀ rẹ̀ lérèfé. Èyí fún wa ní òye nípa ìgbéayé ènìyàn, àyànmọ́, ìgboyà, ìwà-ẹ̀tọ́, ipò àwọn àgbà láwùjọ, ìkìlọ̀, ìmọ̀ràn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ọgbọ́n ìwádìí tí a mú lò fún iṣẹ́ yìí ni ṣíṣe àkójọ àwọn òwe inú Ògbójú. A óò ṣe àlàyé nípa bí D.O. Fágúnwà ti ṣe àmúlò wọn, èyí tí ó mú kí ìwé náà jẹ́ gbajúgbajà láàrin àwọn ìwé ìtàn àròsọ D.O. Fágúnwà àti àwọn ìwé ìtàn àròsọ mìíràn ní ilẹ̀ Adúláwọ̀. A óò wo iṣẹ́ àtinúdá nípa àmúlò òwe tí Fágúnwà ṣe tó mú kí ó jẹ́ akọni òǹkọ̀wé lágbàáyé. A kò ṣàìní wá àwọn ìwé ìtàn àròsọ mìíràn àti átíkù tó dá lórí òwe àti ìwúlò wọn láwùjọ. Wọn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lè ṣe àtúpalẹ̀ iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí tẹ́rùn. Àbájáde iṣẹ́ yìí jẹ́ ká ní ìmọ̀ nípa oríṣìíríṣìí òwe Yorùbá tó wà nínú Ògbójú àti ìwúlò wọn, èyí tó mú kí ìwé Ògbójú ó gbayì. Ó tún túbọ̀ fikún ìmọ̀ wa nípa òwe Yorùbá bí ó ti ṣe kan, ìrísí, oríṣìí, ìhun àti ìlò wọn nípa àṣà, ìṣe àti ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá.
*******
O tema deste artigo são os provérbios presentes na obra *Ogbojou Odê nínú Igbó Irúnmale* (doravante denominada *Ogbojou*), escrita por Daniel Olorunfemi Fágúnwa. Nosso objetivo é destacar a importância e o emprego desses provérbios como recursos linguísticos, culturais e retóricos na obra. Como é sabido, na sociedade iorubá e no continente africano em geral, os provérbios constituem a base da comunicação, servindo como meio de expressão e veículo para transmitir sabedoria, conhecimento e valores morais à comunidade. Em *Ogbojou*, tais provérbios são um elemento fundamental que contribuiu para a popularidade do autor. O uso dessas expressões consagrou Fágúnwa como uma figura de destaque na literatura iorubá entre seus pares. A abordagem teórica adotada para esta análise é multifacetada. A primeira vertente teórica concentra-se no estudo da forma, significado, origem, distribuição, conteúdo e uso dos provérbios. A segunda aborda a tradição oral, analisando como os provérbios são empregados oralmente, em contraposição à forma escrita. A terceira teoria explica a função do provérbio no discurso para além de seu sentido literal, proporcionando uma compreensão sobre a vida humana, o destino, a coragem, a moralidade, o papel dos anciãos na sociedade, bem como sobre advertências, conselhos, entre outros aspectos. A metodologia de pesquisa consiste em compilar os provérbios presentes em *Ogbojou*. Examinaremos a maneira como D.O. Fágúnwa os utilizou — fator que conferiu grande popularidade à obra, tanto em relação aos demais livros do autor quanto no contexto literário do continente africano — e analisaremos a criatividade de Fágúnwa no emprego desses provérbios, o que o projetou como um escritor de renome mundial. Também analisaremos outras obras e artigos que abordam provérbios e seu uso social, subsidiando assim a análise proposta neste artigo. Os resultados deste trabalho permitem ampliar o conhecimento sobre os diversos provérbios iorubás presentes em *Ogbojou* e suas funções, elementos que contribuíram para o sucesso da obra. Além disso, o estudo aprofunda a compreensão dos provérbios iorubás no que tange à sua forma, variedade, conteúdo e aplicação, relacionando-os à cultura, às práticas e às crenças do povo iorubá.
Téléchargements
Références
Adébọ̀wálé, O. àti D. Adélékè (2021). Àkọ̀tun Èdè Ìperí Yorùbá (New Yorùbá Metalanguage). Ìbàdàn: Graceville Publishers.
Adébọ̀wálé, O. àti D. Adélékè àti A. Adéjùmọ̀ (2016). Ọ̀tun Ìmọ̀ Nínú Ìtàn-Àròsọ D.O. Fágúnwà (Findings in the Novels of D.O. Fágúnwà). Lagos: The Capstone Publications.
Adéyẹmí, L. (2012). “Proverbs and Narrative Meaning in Yorùbá Literature”. Paremia Journal, 21, 245-256.
Awóbùlúyì, O. àti O.O. Oyèláràn (2017). Ìléwọ́ Ìkọ̀wé Yorùbá Òde-Òní. Ìlọrin: Kwara State University Press.
Bámgbóṣé, A. (1968). “The Form of Yorùbá Proverbs”. Odu: A Journal of West African Studies, 5, 25-32.
Bámgbóṣé, A. (2007a). The Novels of D.O. Fagunwa: A Commentary. Ìbàdàn: Nelson Publishers Ltd.
Bámgbóṣé, A. (2007b). Symbolism in D.O. Fagunwa’s Novels. Modern Research Studies, 1, 89-90.
Barber, K. (2017). Celebrating D.O. Fágúnwà: Aspect of African and World Literary History. Ìbàdàn: Bookcraft.
Bascom, W. (1969). Ifá Divination: Communication between Gods and Men in West Africa. Bloomington: Indiana University Press.
Beier, U. (1965). The Yorùbá Novel: D.O. Fagunwa. In Introduction to African Literature. Evanston, IL: Northwestern University Press.
Beier, U. (1967). Yorùbá Poetry: An Introduction. Cambridge: Cambridge University Press.
Délànọ̀, I.O. (1966). Òwe Lẹṣin Ọ̀rọ̀. Ìbàdàn: Oxford University Press.
Fágúnwà, D.O. (1938). Ògbójú Ọdẹ Nínú Igbó Irúnmalẹ̀. Lagos: CMS Bookshop.
Fágúnwà, D.O. (1949). Igbó Olódùmarè. London: Thomas Nelson.
Fágúnwà, D.O. (1949). Ìrèké Oníbùdó. London: Thomas Nelson.
Fágúnwà, D.O. (1954). Ìrìnkèrindò Nínú Igbó Elégbèje. London: Thomas Nelson.
Fágúnwà, D.O. (1961). Àdììtú Olódùmarè. London: Thomas Nelson.
Fálétí, A. (1970). Ọmọ Olókùn Ẹṣin. Ìbàdàn: Heinemann.
Finnegan, R. (1970). Oral Literature in Africa. Oxford: Oxford University Press.
Halliday, M.A.K. (1978). Language as Social Semiotic. London: Edward Arnold.
Irele, A. (1981). The African Experience in Literature and Ideology. Ìbàdàn: Heinemann.
Ìṣọ̀lá, A. (2009). Ayé Yẹ Wọ́n Tán. Ìbàdàn: D.G. Mortoy Books.
Lindfors, B. (1982). Critical Perspectives on Nigerian Literatures. London: Heinemann.
Mieder, W. (2004). Proverbs: A Handbook. Westport: Greenwood Press.
Ojo, E.T. (2015). Structure of Proverbs in Selected Yorùbá Written Literature. Ihafa: A Journal of African Studies, 7(1) 161-191.
Òkédìjí, O. (1971). Àgbàlagbà Akàn. Ìbàdàn: Longman Nigeria Ltd.
Owólabí, K. (2001). Essential of Yorùbá Grammar. Ìbàdàn: University Press Plc.
Soyinka, W. (1968/2013/(Trans.) Forest of a Thousand Daemons: A Hunter’s Saga. London/Ìbàdàn: Thomas Nelson and Sons/Bookcraft.
Unilag Stylistic Study (2015). A Stylistic Study of Proverbs and Idioms in the translated Novels of D.O. Fágúnwà.
Téléchargements
Publiée
Comment citer
Numéro
Rubrique
Licence
© NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras 2026

Ce travail est disponible sous licence Creative Commons Attribution - Pas d'Utilisation Commerciale - Pas de Modification 4.0 International.
Les auteurs qui publient dans cette revue acceptent les conditions suivantes:
Les auteurs conservent le droit d'auteur et accordent à la revue le droit de première publication, l'œuvre étant simultanément concédée sous licence Creative Commons Attribution License, qui permet le partage de l'œuvre avec reconnaissance de la paternité de l'œuvre et publication initiale dans ce magazine.
Les auteurs sont autorisés à assumer séparément des contrats supplémentaires, pour la distribution non exclusive de la version de l'ouvrage publié dans cette revue (par exemple, publication dans un référentiel institutionnel ou en tant que chapitre de livre), avec reconnaissance de la paternité et publication initiale dans cette revue.
Les auteurs sont autorisés et encouragés à publier et distribuer leurs travaux en ligne (par exemple dans des référentiels institutionnels ou sur leur page personnelle) à tout moment avant ou pendant le processus éditorial, car cela peut générer des changements productifs, ainsi que citation des travaux publiés (voir l'effet du libre accès).