Ìfìwàwẹ̀dá obìnrin gẹ́gẹ́ bí akọni nínú àṣàyàn eré-onítàn Yorùbá
The portrayal of women as heroines in a selection of Yoruba historical dramas
Palabras clave:
Akọni, Eré-onítàn, Ìṣẹ̀tọ́fábo, Obìnrin, YorùbáResumen
Iṣẹ́ ìwádìí yìí ṣe àgbéyẹ̀wò ipa obìnrin gẹ́gẹ́ bí akọni nínú àwọn àṣàyàn ìwé eré-onítàn Yorùbá. Ó ṣe àfàyọ ipa tí àwọn obìnrin kó àti ipò tí wọ́n wà, èyí tí ó fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí akọni bí ó ṣe jẹ yọ nínú àwọn ìwé eré-onítàn tí a ṣà yàn fún iṣẹ́ yìí. Èrèdí ṣiṣe èyí láti ṣe àgbéyẹ̀wò irúfẹ́ àwọn ipò tí ó jẹ́ ipò akọni tí àwọn òǹkọ̀wé eré-onítàn Yorùbá to àwọn ẹ̀dá-ìtàn tí wọ́n jẹ́ obìnrin sí nínú àwọn àṣàyàn iṣẹ́ wọn. Àwọn ìwé eré-onítàn tí iṣẹ́ yìí ṣe àmúlò jẹ́ mẹ́fà, àwọn ìwé eré-onítàn náà sì ni Mọrèmi, Ẹfúnṣetán Aníwúrà, Olú Ọmọ, Baṣọ̀run Gáà, àti Orí Mẹ̀kúnnù. Ìtupalẹ̀ iṣẹ́ yìí gbára lé ìlànà tíọ́rì ìṣẹ̀tọ́fábo. Iṣẹ́ yìí jẹ́ kí ó hàn pé àwọn òǹkọ̀wé eré-onítàn Yorùbá gbé àwọn obìnrin kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọni láàrin àwùjọ nínú aáyan ogun jíjà àti ètò ìṣèlú àwùjọ, èyí jẹ yọ nínú ipa tí àwọn òǹkọ̀wé jẹ́ kí àwọn ẹ̀dá-ìtàn tí wọ́n jẹ́ obìnrin kó nínú àwọn ìwé eré-onítàn náà. Àwọn kókó-ọ̀rọ̀ tí ó fojú hàn nípa obìnrin ní ipò akọni ni obìnrin gẹ́gẹ́ bí akọni jagunjagun, obìnrin gẹ́gẹ́ bí akọni olóògùn, obìnrin gẹ́gẹ́ bí akọni ajìjàgbara, obìnrin gẹ́gẹ́ bí akọni-dòrìṣà àti obìnrin gẹ́gẹ́ bí akọni nípa ìlò agbára ẹ̀mí àìrí. Iṣẹ́ yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé fífi àwọn obìnrin hàn gẹ́gẹ́ bí akọni nínú àwọn ìwé eré-onítàn Yorùbá jẹ́ ọnà láti fa ògo ìjobìnrin yọ, ó sì jẹ́ àfihàn àwòràn bí àwọn obinrin ṣe rí gan-an nínú àwùjọ Yorùbá.
*******
This study examines women’s roles as heroines in selected Yorùbá plays. It identified the women roles and their postions as potray in the selected plays for this study with a view to examining the various heronic positions that the Yorùbá playwrights give to female characters in their works. The study examines six Yorùbá plays, which are: Mọrèmi, Ẹfúnṣetán Aníwúrà, Olú Ọmọ, Baṣọ̀run Gáà and Orí Mẹ̀kúnnù and it employed the theory of womanism for the analysis. Findings of the study revealed that Yorùbá playwrights potray women as heroines in war organisation and social politics, as it is evident in the roles that women play in the selected Yorùbá plays. The themes identified were women as heroine in war fighting, charm casting, activism, legendary and the use of spiritual power. This study affirms that potraying women as heroines in Yorùbá plays exhumes women glory and depicts their true picture in Yorùbá society.
Descargas
Citas
Adágbádá, O. (2005). “Womenfolk in Yorùbá film industry”. Unpublished Ph.D.Thesis Submitted to the Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan, Ibadan.
Adébọ̀wálé, O. (1999a). Ọgbọ́n Òǹkọ̀wé alátinúdá. Ìbàdàn: The Capstone Publishers.
Adémúyìwá, A. (2014). “Àgbéyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Jẹ́ńdà nínú Ewì Ọlánrewájú Adépọ̀jù”. Unpublished B.A. Long Essay submitted to the Department of Linguistics and African Languages, Obafemi Awolowo University, Ilé-Ifẹ̀.
Adéoyè, C. L. (2010). Àṣà àti Ìṣe Yorùbá. Ìbàdàn: University Press PLC.
Ajíbádé, G. O. (2005). Negotiating Performance: Osun In Verbal and Visual Metaphor. Bayreuth: University of Bayreuth.
Àjùwọ̀n, J. (2017). “Ìtúpalẹ̀ Àṣàyàn Oríkì àwọn Akọnikùnrin àti Akọnibìnrin Yorùbá ní Ìwọ̀ Oòrùn Gúúsù Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà”. Unpublished PhD. Thesis submitted to the of Department of Linguistics and African Languages, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.
Akínlàdé, K. (2006). Gbọ̀nǹkáà Ẹkùn Àbìjàwàrà. Ìbàdàn: Providence Multi-Publisher.
Akínyẹmí, A. (2004a): “Yorùbá oral literature: A Source of Indigenous Education for Children”.
Owólabí àti Dasylva (ol.) Form and Functions of English and Indigenous Languages in Nigeria. Ìbàdàn: Group Publishers.
Fálétí, A. (1976). Baasọ̀run Gáá. Ìbàdàn: Onibon-Oje Press and Book Industries.
Fánílọlá, K. (1999). Orí mẹ̀kúnnù. Ìbàdàn: Tafak Publications.
Ìṣọ̀lá, A. (1970). Efúnṣetán Aníwúrà. Ìbàdàn: University Press Ltd.
Iṣọ̀lá, A. (1983). Olú Ọmọ. Ìbàdàn: Onibon-Oje Press and Book Industries.
Ládipọ̀, D. (1971). Mọrèmi. Lagos: Macmillan and Co. Nigeria Ltd.
Ògúnníran, L. (1977). Àtàrí Àjànnàkú. Ìbàdàn: Onibon-Oje Press and Book Industries.
Ògúnníran, L. (2006). Ààrẹ Àgò Aríkúyẹrí. Ìbàdàn: Macmillian Nigeria Publishers Ltd.
Descargas
Publicado
Cómo citar
Número
Sección
Licencia
Derechos de autor 2026 NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras

Esta obra está bajo una licencia internacional Creative Commons Atribución-NoComercial-SinDerivadas 4.0.
Los autores que publican en esta revista aceptan los siguientes términos:
Los autores mantienen los derechos de autor y otorgan a la revista el derecho a la primera publicación, siendo el trabajo simultáneamente licenciado bajo la Licencia de Atribución Creative Commons, que permite compartir el trabajo con reconocimiento de la autoría del trabajo y la publicación inicial en esta revista.
Se autoriza a los autores a asumir contratos adicionales por separado, para la distribución no exclusiva de la versión del trabajo publicado en esta revista (p. Ej., Publicación en repositorio institucional o como capítulo de libro), con reconocimiento de autoría y publicación inicial en esta revista.
Se permite y se anima a los autores a publicar y distribuir su trabajo en línea (por ejemplo, en repositorios institucionales o en su página personal) en cualquier momento antes o durante el proceso editorial, ya que esto puede generar cambios productivos, así como aumentar el impacto y cita del trabajo publicado (Ver El efecto del acceso abierto).