Ọgbọ́n ìṣẹ̀dá àti àwòmọ́ afọ̀: ìlànà fún ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá
Sabedoria natural e o olhar de quem vê: um guia para analisar a literatura oral iorubá
Palabras clave:
Litireso, Oriki, Ogbon Agbekale, Ibile EnuResumen
ÀṢAMỌ̀
Láti ibi ète ìṣẹ̀dá ni ìbẹ̀rẹ̀ ìgbéjáde ẹ̀yà lítíréṣọ̀ yòówù ti máa ń wáyé, èyí sì máa ń gba ìrònújinlẹ̀ àti ọgbọ́n àtinúdá oníṣẹ́-ọnà lítíréṣọ̀. Nígbà tí ìṣẹ̀dá lítíréṣọ̀ bá kalẹ̀ tán, ó ni àwọn àbùdá àti àwòmọ́ afọ̀ kan tí oníṣẹ́-ọnà lítíréṣọ̀ gbọdọ̀ dì mẹ́rù nínú ìgbéjáde ìpohùn tàbí ìṣèré rẹ̀. Ìdí ni pé àwọn àwòmọ́ afọ̀ yìí ni wọ́n máa ń jẹ́ àwòmọ́ ìdájọ́, èyí tí àwọn òǹwòran tàbí òǹgbọ́ máa ń lò gẹ̀gẹ̀ bí òṣùwọn tàbí òté láti ṣe ìdájọ́ irúfẹ́ ẹ̀yà ìpohùn kan tàbí apohùn kan pàtó. Onírúurú ète tí àwọn apohùn ń lò fún ìṣẹ̀dá ìpohùn ni a pè ní ‘ọgbọ́n ìṣẹ̀dá’, àwọn àbùdá tí ó sì jẹ́ àwòmọ́ ìdájọ́ ni a tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí ‘àwòmọ́ afọ̀’. Àwọn kókó-èrò méjì yìí ni ó dàbí òpó tí ó di lítíréṣọ̀ Yorùbá mú. Lámèétọ́ sì lè ṣe àmúlò wọn gẹ́gẹ́ bí tíọ́rì tàbí ìlànà tí yóó le ṣe àyẹ̀wò aáyan apohùn àti ìmúradè àwọn òǹwòran tàbí òǹgbọ́. A ṣe àmúlò ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn ìpohùn Yorùbá bí oríkì, àlọ́, òwe, ewì àwíṣẹ, ewì ajẹmọ́fá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, fún ìtúpalẹ̀ àti àlàyé nínú iṣẹ́ yìí. A sì lo ìlànà fọ́múlà ìpohùn (oral formulaic approach) gẹ́gẹ́ bí ojúpọ̀nnà ìtúpalẹ̀. Iṣẹ́ yìí jẹ́ kí ó hàn pé ṣíṣe àwòpọ̀ ọgbọ́n ìṣẹ̀dá àti àwòmọ́ afọ̀ fún ìtúpalẹ̀ lítíréṣọ̀ alohùn yóó ṣe ìhújáde àwọn àwòmọ́ ajẹmẹ́wà ìpohùn Yorùbá àti ti Áfíríkà lápapọ̀.
Descargas
Citas
Ìwé Ìtọ́kasí
Abímbọ́lá, W. (1967). Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá: Apá kìíní. Glasgow: Collins
Adémúyìwá, A. L. (2017) “Ìtúpalẹ Ìṣọwọ́lò-Èdè Nínú Àṣàyàn Ewì Ọláńrewájú Adépọ̀jù”. M.A. Thesis, Department of Linguistics and African Languages. Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University. Ilé-Ifẹ̀.
Adémùyíwá, A. L. (2022). “A Critical Analysis of Thematic and Stylistic Features in
Oríkì of Towns in Òkè-Ògùn”. Unpublished Ph.D. Thesis, Department of
Linguistics and African Languages. Ọbáfẹ́mi Awólówọ̀ University, Ilé-Ifè.
Adépọ̀jù, O. (1972). Ìrònú Akéwì. Ìbàdàn: Onibonoje Press & Book Industries.
Akìwọwọ, O. (1986). Àsùwàdà-ènìyàn nínú Àjùwọ̀n, B. (ed) Ifẹ Annals of Cultural Institute, Obafemi Awolowo University Press, Ile-Ife.
Ajíbádé, G.O. àti Rájí S.M. (2011). Ewì Àlàbí Ògúndépò. Ìbàdàn: Alafas Nigeria Company.
Ajuwọn, J.A. (2013). ‘Àrọ́: Ipèníjà tó fẹjú’ LAANGBASA: Jọ́nà Iṣẹ́ Akadá ni Èdè Yorùbá. No. 17. University of Lagos. Pp. 96-106
Bamgbose, A. (1967). ‘The form of Yorùbá Proverbs’ Odù: Journal of Yorùbá and Related Studies, 3, 9-26.
Burke, M. (2013). “Rhetoric and Poets: The classic heritage of stylistics” Ninu Burke, M (ed) The Routledge Handbook of stylistics. New York: Routledge.
Iṣọla, A. (1978). Àfàìmọ̀ àti àwọn Àròfọ̀ Míràn. Ìbàdàn: University Press Limited.
Jamil, M.B. and Yang, Y. (2012). A Case Study of the Novel, Siddhartha from the Perspective of Intertexuality. Journal of Education and Practice. Vol.3, no. 14. Pp. 141-147
Olasebikan, A.I. (2023). Ojú À̀múwayé Yorùbá nínú Àsàyàn Òwe Ajẹmọ́-Aìsàn àti Ipèníjà ara ni Àwùjọ Yorùba. (An Appraisal of Yorùbá worldview on Sickness and disabilities in Selected Yorùbá Proverbs). Unpublished M.A Thesis, Department of Linguistics and African Languages, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.
Ọlátúnjí Ọ. (1982a). Ewì Adébáyọ̀ Fálétí Ìwé Kínní. Ibadan: Heinemann Educational Books (Nig.) Limited.
Ọlátúnjí, Ọ́. (1982b). “Classification of Yorùbá Oral Poetry” Afọ́láyan, A (ed). Yorùbá Language and Literature. Pp. 57-81.
Ọlátúnjí, O. O. (1984). Features of Yorùbá Oral Poetry. Ìbàdàn: University Press Ltd.
Ológundúdú, K. (2009). Adé Orí Ọ̀kín: Àṣàyàn Ewì Oríkì, pẹ̀lú Àlàyé Lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ìbàdàn: Penthouse Publications (Nig.).
Ọ̀pádọ̀tun, O. (2003). Òǹkọwe àti Ìwé Kíkọ Alátínudá. Oyo. Odumatt Publishers.
Descargas
Publicado
Cómo citar
Número
Sección
Licencia
Derechos de autor 2025 NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras

Esta obra está bajo una licencia internacional Creative Commons Atribución-NoComercial-SinDerivadas 4.0.
Los autores que publican en esta revista aceptan los siguientes términos:
Los autores mantienen los derechos de autor y otorgan a la revista el derecho a la primera publicación, siendo el trabajo simultáneamente licenciado bajo la Licencia de Atribución Creative Commons, que permite compartir el trabajo con reconocimiento de la autoría del trabajo y la publicación inicial en esta revista.
Se autoriza a los autores a asumir contratos adicionales por separado, para la distribución no exclusiva de la versión del trabajo publicado en esta revista (p. Ej., Publicación en repositorio institucional o como capítulo de libro), con reconocimiento de autoría y publicación inicial en esta revista.
Se permite y se anima a los autores a publicar y distribuir su trabajo en línea (por ejemplo, en repositorios institucionales o en su página personal) en cualquier momento antes o durante el proceso editorial, ya que esto puede generar cambios productivos, así como aumentar el impacto y cita del trabajo publicado (Ver El efecto del acceso abierto).