Àfihàn Akitiyan Akọnibìnrin Mọrèmi Àjàṣorò Nínú Ìwé Eré-Onítàn Mọrèmi tí Dúró Ládipọ̀ Kọ àti Ìdàgbàsókè Àwọn Obìnrin ní Àwùjọ Áfíríkà

O Ativismo da Heroína Moremi Ajasoró no Livro *Morémi: Stories that Stand Together* e o Desenvolvimento das Mulheres na Sociedade Africana

Authors

  • Mercy Ayọ̀ FASEHUN Adéyẹmí Federal University of Education, Oǹdó, Nigeria
  • Ìlúfóyè Fáwọlé ÒJÓ Adéyẹmí Federal University of Education, Oǹdó, Nigeria

Keywords:

Akọnibìnrin, Àwùjọ, Eré-onítàn, Ìdàgbàsókè, Ìṣègbèfábo, Tíọ́rì Máàsì

Abstract

Ipa mánigbàgbé tí akọnibìnrin Mọrèmi kó nínú àwùjọ rẹ̀, Ilé-Ifẹ̀, Nàìjíríà àti bí àwọn ipa tí ó ti kó wọ̀nyí ti ṣe ń fara hàn nínú irú ipa tí àwọn obinrin ní ilẹ̀ Áfíríkà náà ń kó ní àwùjọ wọn lóde òní, ni àfojúsùn iṣẹ́ yìí. Iṣẹ́ ìwádìí yìí wo ìtumọ̀ akọni ní àwùjọ Yorùbá. Iṣẹ́ yìí ṣe ìtúpalẹ̀ ìtàn akọnibìnrin Mọrèmi, ipa ribiribi tí ó kó nínú ètò ọrọ̀-ajé, ètò ìṣèlú àti ètò amúlùúdùn ní àwùjọ Ilé-Ifẹ̀. Bákan náà, iṣẹ́ yìí tún ṣàlàyé kíkún nípa ète àti agbára tí akinbìnrin Mọrèmi lò láti gba àwọn ènìyàn Ilé-Ìfẹ́ sílẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn tí àwọn Ìgbò/Ùgbò ti fi wọ́n sí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, kí àlàáfíà tó padà jọba láwùjọ Ilé-Ifẹ̀. Iṣẹ́ yìí tún ṣe àfihàn èrò àwùjọ nípa obìnrin àti bí ìwà akíkanjú Mọrèmi ti ṣe jẹ́ àwòkọ́ṣe rere ńlá fún àwọn obìnrin ilẹ̀ Áfíríkà láti lè kópa mánigbàgbé nínú ìdàgbàsókè àwùjọ wọn. Ọgbọ́n ìṣèwádìí mẹ́ta ni a lò láti ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ ìwádìí yìí. Ní àkọ́kọ́, a ka ìwé eré-onítàn Mọrèmi  dáadáa láti lè fa àwọn kòmóòkun inú eré-onítàn náà yọ.  Ní ẹ̀kejì, a ṣe àgbékalẹ̀ ìtàn Mọrèmi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe hàn nínú ìwé eré-onítàn Mọrèmi. Ní ẹ̀kẹta, a fi ọ̀rọ̀ wá àwọn òpìtàn mẹ́rin lẹ́nu wò; ẹnìkan ní Ilé-Ifẹ̀ (ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun), ẹnìkan ní Ọ̀fà (ìpínlẹ̀ Kwara), ẹnìkan ní ilẹ̀ Ìgbò ( Ùde-Ùgbò) àti ẹnìkan ní Odòde/Òde Ìdànrè (ìpínlẹ̀ Oǹdó) láti lè ní òye nípa ìtàn ìwáṣẹ̀ tí ó ṣọ nípa rẹ̀.   Àwọn àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò wọ̀nyí ni a ṣe ìtúpalẹ̀ wọn ní ìlànà Tíọ́rì Karl Marx tí ó sọ̀rọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé, tíọ́rì ìṣègbèfábo/ìṣẹ̀tọ́fábo tí ó sọ nípa ìjìjàgbara àwọn obìnrin àti ipa wọn láwùjọ.  Àgbálọgbábọ̀ iṣẹ́ ìwádìí yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bí àwọn òǹkọ̀wé eré-onítàn Yorùbá ti ṣe ń fi ìwà akin àwọn obìnrin hàn nínú lítíréṣọ̀ bẹ́ẹ̀ náà ni ó ń fi ara hàn ní ojú ayé. Èyí fi hàn pé ipò àwọn obìnrin àti ipa tí wọ́n ń kó láàrin àwùjọ kò ṣé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá. Iṣẹ́ yìí dá a lábàá pé kí àwọn obìnrin Áfíríkà wo àwòkọ́ṣe Mọrèmi kí wọ́n sì máa mú un lò fún ìdàgbàsókè àwùjọ wọn.

******* 

O foco deste estudo é o papel inesquecível desempenhado pela heroína Moremi em sua comunidade, Ile-Ife (Nigéria), e como essas ações se refletem no papel que as mulheres africanas desempenham em suas comunidades atualmente. A pesquisa examina o significado da figura da heroína na sociedade iorubá, analisando a história de Moremi e o papel fundamental que ela desempenhou nos sistemas econômico, político e social de Ile-Ife. Além disso, o estudo detalha o propósito e o poder empregados por Moremi para libertar o povo de Ile-Ife do cativeiro imposto pelos Igbo/Ugbo por muitos anos, até o retorno da paz à sociedade local. O trabalho também revela a percepção social sobre as mulheres e como a bravura de Moremi serve de exemplo para que as mulheres africanas contribuam significativamente para o desenvolvimento de suas sociedades. Três métodos de pesquisa foram utilizados: primeiramente, realizou-se uma leitura atenta da obra literária sobre Moremi para extrair seus elementos essenciais; em seguida, apresentou-se a história de Moremi conforme retratada na referida obra; por fim, entrevistaram-se quatro historiadores — localizados em Ile-Ife (Estado de Osun), Ofa (Estado de Kwara), Igbo (Úde-Úgbho) e Odode/Óde Idanre (Estado de Ondo) — para compreender a história da luta associada a ela. Esses estudos de caso foram analisados ​​à luz da Teoria Econômica de Karl Marx e da Teoria do Feminismo/Etnicidade, que aborda a luta das mulheres e seu papel na sociedade. Os resultados confirmam que a natureza heroica das mulheres, retratada por dramaturgos iorubás na literatura, também se manifesta no mundo real. Isso demonstra que o status da mulher e seu papel na sociedade não foram negligenciados. O trabalho sugere que as mulheres africanas devem considerar o modelo de Moremi e utilizá-lo em prol do desenvolvimento de suas sociedades.

Downloads

Download data is not yet available.

Author Biographies

Mercy Ayọ̀ FASEHUN, Adéyẹmí Federal University of Education, Oǹdó, Nigeria

Is an Associate Professor in the Department of Yorùbá, Adeyemi Federal University of Education, Oǹdó. She holds both MA and PhD degrees in Yorùbá Literature from premiere University of Ibadan, Nigeria. She is a member of Ẹgbẹ́-Onímọ̀ Èdè Yorùbá (Yorùbá Studies Association of Nigeria (YSAN) and Ẹgbẹ́ Ọ̀mọ̀ràn Èdè Yorùbá (Association of Yorùbá Language Scholars) (ASSYLAS).  Her academic background, teaching and research interests include Yorùbá literature and culture. Her research work focuses on indigenous performances at Ọ̀ràmfẹ̀, Ògún and Ọba festivals of Oǹdó Kingdom. Her articles on Yorùbá literature and culture have been published in IOSL Journal of Humanities and Social Science (IOSR – JHSS)International Journal of Sustainable Development and reputable books within and outside Nigeria. She has made academic presentations at local and international conferences.

Ìlúfóyè Fáwọlé ÒJÓ, Adéyẹmí Federal University of Education, Oǹdó, Nigeria

is a Senior Lecturer in the Department of Yorùbá, Adéyẹmí Federal University of Education, Oǹdó He holds B.A (Ed,), M.A. and PhD in Yorùbá Language and Literature from Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria. He is a member of Ẹgbẹ́-Onímọ̀ Èdè Yorùbá (Yorùbá Studies Association of Nigeria) and Ẹgbẹ́ Ọ̀mọ̀ràn Èdè Yorùbá (Association of Yorùbá Language Scholars). He has published articles in various reputable local and international journals like IOSL Journal of Humanities and Social Science (IOSR – JHSS) and Njinga & Sepé, Revista International de Culturas, Linguas Africanas e Brasileiras. He has co-authored textbooks in Yorùbá oral literature, contributed chapters to some books, and attended local and international conferences. His research interest is in the areas of Yorùbá oral literature, folklore, Yorùbá culture and stylistics.

References

Adéyẹmí, L. (2006). Tíọ́rì lítíréṣọ̀ ní èdè Yorùbá. Shẹ́bíòtímọ́ Publications.

Ajíbádé, G. O. (2009). Finding female voice: a socio-cultural appraisal of Yorùbá nuptical poetry. Rudiger Koppe Verlag Kln.

Àjùwọ̀n, J. (2017). Ìtúpalẹ̀ àṣàyàn oríkì àwọn akọni-kùnrin àti akọni-bìnrin Yorùbá ní ìwọ̀-oòrùn gúúsù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (Unpublished doctoral dissertation, Obafemi Awolowo University).

Akínyẹmí, A. (1991). Ìlò oríkì láwùjọ Ọ̀yọ́ (Unpublished doctoral dissertation, Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ University).

Althusser, L. (1977). For Marx. Methuen.

Àrẹ̀mú, P. S. O. (2022). Dúró Ládipọ̀’s Mọrèmi: Myth, history and the Nigerian stage. Journal of African cultural studies, 34 (3), 287-301.

Barber, K. (1979). Oríkì and social structure (Unpublished doctoral dissertation, University of Ifẹ̀).

Davies, B., & Graves, A. A. (1986). Ngambika: Studies of women in African literature. Africa World Press.

Eagleton, T. (1976a). Marxism and literary criticism. Methuen.

Eagleton, T. (1976b). Criticism and ideology. Methuen.

Engels, F. (1975). On Marx. Foreign Languages Press.

Hook, S. (2006). The hero in history: A study in limitation and possibility. Hesperides Press.

Hooks, B. (1985). Feminist theory: From margin to center. South End Press.

Hudson-Weems, C. (1998). African womanism. Garland.

Johnson, S. (1921). The history of the Yorubas. CMS Bookshops.

Kọ́láwolé, M. E. M. (1997). Womanism and African consciousness. Africa World Press.

Ládiípọ, D. (1971). Mọrèmi. Macmillan Nigeria.

Lenin, V. I. (1997). Karl Marx (Vol. 12). Progress Publishers.

Marx, K., & Engels, F. (1977). Manifesto of the Communist Party. Progress Publishers.

Nash, J. C. and Pinto, S. (2025). Beyond first, faith, family, and fidelity: Living inside inter-generational feminist engagement. Feminist theory, 26 (3), 202-210.

Ôgúndípẹ̀-Leslie, M. (2021). Re-creating ourselves: African woman and critical transformations African literature today, 39, 1-15.

Oyèwùmí, O. (2020). The invention of women: Making an African sense of Western gender discourses (20th Anniversary ed.). University of Minnesota.

Ọlọ́runtọ́ba-Oju, T. (2023). Yorùbá oral performance and feminist consciousness in contemporary Nigerian drama. Research in African literatures, 54 (1), 45-62.

Ọ̀pẹ́fèyítìmí, A. (2016). Tíọ́rì àti ìṣọwọ́lò-èdè. Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University.

Rájí, S. M. (2000). Ìbágbàmu tíọ́rì aṣègbèfábo. Ọ̀gẹ̀gẹ́: Journal of Yorùbá language and culture, 1, 101-106.

Rájí, S. M., & Òjó, I. F. (2014). Trends in women’s education and political development in Nigeria: A feminist approach. In O. Atóyèbí et al. (Eds.), Management of tertiary institutions for qualitative education (pp. 448-466). Spectrum Books.

Siddiqui, K. (2024). Marxian analysis of capitalism and crises. International critical thought, 13, (4), 525-545.https://doi.org/10.1080/215-98282.2023.2296167.

Shang, A. (2018). Who are heroes? An analysis of the literary hero (Undergraduate thesis, University of Texas at Austin).

Su, W. (2024). Understanding heroes from psychological and cultural perspectives. Journal of humanities and social science, 8(9), 2228–2234.

Published

27-08-2026

How to Cite

FASEHUN, M. A., & ÒJÓ, Ìlúfóyè F. (2026). Àfihàn Akitiyan Akọnibìnrin Mọrèmi Àjàṣorò Nínú Ìwé Eré-Onítàn Mọrèmi tí Dúró Ládipọ̀ Kọ àti Ìdàgbàsókè Àwọn Obìnrin ní Àwùjọ Áfíríkà : O Ativismo da Heroína Moremi Ajasoró no Livro *Morémi: Stories that Stand Together* e o Desenvolvimento das Mulheres na Sociedade Africana. NJINGA&SEPÉ: evista nternacional e ulturas, Línguas fricanas rasileiras, 6(Especial III), 80–100. etrieved from https://revistas.unilab.edu.br/njingaesape/article/view/2945