Ìtúpalè̩ Ìs̩àfihàn Èrò Ìjìnlè̩ nípa Agbára Olódùmarè, Ìsò̩rí Ìs̩è̩dá Abè̩mí, àti Aje̩mé̩ranko nínú Ìlò Oríkì

A Socio-Cultural Analysis of Power of Creator, Creatures, and Animatory Creatures through the use of Oríkì

Authors

Keywords:

Ìran Yorùbá, Èrò Ìjìnlè̩, Agbára Olódùmarè, Ìs̩è̩dá Abè̩mí, àti Ìlò Oríkì

Abstract

ÀS̩AMÒ̩

Onírúúrú àkíyèsí ni ó ti wà s̩aájú is̩é̩ ìwádìí yìí tí ó fi hàn pé, ìran Yorùbá jé̩ ìran kan tí wó̩n kún fún àkíyèsí, àti àròjinlè̩ nípa àyíká wo̩n. Bákan náà ni pé, ìran Yorùbá kún fún àròjinlè̩ nípa ìgbésí ayé tí wo̩n ń gbé. Àìdé̩ye̩ sí ìgbàgbó̩ nínú èrò ìjìnlè̩ wo̩n pé Olódùmarè ni orí fún gbogbo ìs̩è̩dá, yálà abè̩mí, tàbí aláìlé̩mìí jé̩ ohun tí wó̩n máa ń fi hàn níbikíbi ti wó̩n bá ti ní ànfààní. Ní pàtàkì, wó̩n ń s̩e àfihàn àwo̩n nǹkan ìs̩è̩dá o̩wó̩ Olódùmarè nínú ìlò oríkì tí wó̩n máa ń s̩è̩dá. Èyí hàn gbangba nínú oríkì tí wó̩n ń hun fún àwo̩n ohun ìsò̩rí abè̩mí aje̩mé̩ranko tí wó̩n gbà pé Olódùmarè dá, tí ènìyàn ń sìn, èyí tí wo̩n kì í sìn, àti àwo̩n è̩dá inú omi. Nítorí náà, nínú is̩é̩ ìwádìí yìí, a tó̩ka sí aagbo̩n ìs̩àmúlò oríkì gé̩gé̩ bí abala kan pàtàkì tí Yorùbá fi ń fi àròjinlè̩ wo̩n hàn nípa nǹkan àyíká wo̩n, tí ó je̩ mó̩ ìs̩e, ìhùwàsí àti àkíyèsí wo̩n, nípa àwo̩n ìsò̩rí ìs̩è̩dá abè̩mí àti àwo̩n ìs̩è̩dá aje̩mé̩ranko àyíká wo̩n. Ìlànà ìwádìí tí a lò ni s̩ís̩e àkójo̩ àwo̩n àròfò̩, oríkì àti orin àwo̩n apohùn fún àwota. A s̩e àgbéyè̩wò àkóónú ìpèdè oríkì tí ó gbajú-gbajà tí àwo̩n apohùn hun jo̩, fún àfihàn àwo̩n ìje̩lógún èrò is̩é̩ yìí. A s̩e àgbéyè̩wò ò̩pò̩lo̩pò̩ àwo̩n oríkì tí ó wà lórí àwo̩n ìsò̩rí ìs̩è̩dá abè̩mí tí a s̩à yàn fún àlàyé kíkún. Tíó̩rì Ìfojú-Às̩à-Ìbílè̩-wo is̩é̩-o̩nà lítírésò̩ ni a fi s̩e àwòta fún ìtúpalè̩ láti fi hàn pé, èrò àròjinlè̩ nípa ìs̩esí, ìhùwàsí àti ìrísí àwo̩n ìs̩è̩dá abè̩mí tí a tó̩ka sí nínu is̩é̩ yìí, ni ó bí ìlànà ìhun oríkì tí ìran Yorùbá s̩e àgbékalè̩ rè̩. Is̩é̩ yìí túnbò̩ fi òye kíkún hàn nípa bí ìgbàgbó̩ ìran Yorùbá s̩e lóòrìn tó, nípa ìpèdè “As̩è̩dá, Olúdá ayé àti ò̩run, àti “Olùdá ohun gbogbo” tí àwo̩n onímò̩ kan ti fún Olódùmarè. è̩wè̩, a se àfihàn bí ìran Yorùbá s̩e ní ìgbàgbó̩ púpò̩ nínú agbára Olódùmarè, Ìyà mi, àjo̩s̩epò̩, àti ojús̩e àwo̩n nǹkan abè̩mí sí ara won nínú ìpèdè oríkì tí a se ìtúpalè̩ nínú is̩é̩ àpilè̩ko̩ yìí láti fi ìdí èrò múlè pé, ìsesí, ìhùwàsí àti àwo̩n àbùdá è̩dá kò̩ò̩kan ni ó ń ran alátinúdá ló̩wó̩ fún ìhun oríkì tí wó̩n ń hun.

 *****

Houve várias observações antes desta pesquisa que mostram que o povo iorubá é um povo repleto de observações e imaginação sobre seu ambiente. Da mesma forma, o povo iorubá é repleto de imaginação sobre a vida que leva. A crença profunda de que Deus é a cabeça de toda a criação, seja animada ou inanimada, é algo que demonstram sempre que têm oportunidade. Em particular, demonstram as criações de Deus por meio da poesia que criam. Isso é evidente na poesia que compõem para as criaturas que acreditam ter sido criadas por Deus, aquelas que adoram, aquelas que não adoram e as criaturas aquáticas. Portanto, nesta pesquisa, nos referimos ao uso da poesia como um aspecto importante da maneira iorubá de expressar seus pensamentos sobre seu ambiente, ou seja, suas ações, comportamentos e observações sobre as criaturas da natureza e as criaturas de seu ambiente. O método de pesquisa utilizado foi coletar poemas, canções e cânticos dos poetas para o propósito do estudo. O conteúdo dos poemas mais populares escritos pelos poetas foi analisado para demonstrar os dez princípios deste estudo. Diversos poemas sobre o tema da criação da alma foram analisados e selecionados para uma análise detalhada. A teoria da perspectiva nativa americana sobre obras literárias é utilizada como estrutura para o estudo, a fim de demonstrar que a profunda compreensão das ações, comportamentos e aparência das criaturas mencionadas nesta obra deu origem aos princípios poéticos sobre os quais o povo iorubá se baseou. Este trabalho também demonstra uma compreensão completa do quanto o povo iorubá acredita na poesia, por meio da linguagem de "As̩è̩da", "Oludu aya at ô̩rún" e "Oludu ohun gbogbo", que alguns estudiosos atribuíram a Olódùmarè. Neste trabalho, demonstramos o quanto o povo iorubá acredita no poder de Olódùmarè, Iyà mi, àjo̩epo̩ e nas responsabilidades dos seres vivos uns para com os outros, na linguagem poética apresentada neste artigo, para estabelecer a ideia de que as ações, os comportamentos e as características de cada criatura são o que os poetas usam para tecer a poesia que tecem.

 

Downloads

Download data is not yet available.

Author Biography

Adéo̩lá Adijat FÁLÉ̩YE , Obafemi Awolowo University, Ilé-Ifè, Òsun, Nigeria

Fellow of the American Council of Learned Scholars, Lecturer @ Department of Linguistics and African Languages, Faculty of Arts, Obafemi Awolowo University, Ilé-Ifè, Òsun,  Nigeria

References

Àkójo̩pò̩ Orúko̩ Ìwé

Adeoye, C.L. (1982). Orúko̩ Yorùbá. Ìbàdàn: University Press Plc.

Adepoju, O. (1989). Ìrònú Akéwì. Ibadan: Ò̩nìbo̩n-Òjé Press and Book Industries (Nig) Ltd.

Ajayi, O. (2011). “Agbéyè̩wò Oríkì Àwo̩n Às̩àyan E̩ranko nínú Ìjálá àti Ìrèmòjé”.

Unpublished Masters dissertàtion, O̩báfé̩mi Awólo̩wò̩ University, Ilé-Ifè̩.

Ajíbádé, G.O. (2005). “Animal in the Traditional Worldview of the Yorùbá” Folklore 30:3,

-172.

Ajayi O, àti Ajíbádé, G.O (2021). Ìtúpalè̩ Às̩àyan Oríkì E̩ranko. Yorùbá Studies Review. Volume 6,

Number 1, Spring 2021. 209-233.

Akínyemí, A. (2015). Yorùbá Royal Poetry: A Socio-historical Exposition and Annotated

Translation. Bayreuth African Studies Series (BASS), 71, 2004).

Akínyemí, A. (1993) Ìlò Oríkì Láwùjo Ilú Òyó. Unpublished PhD thesis of the African

languages and Literatures Department. University of Ife.

Àrè̩mú, A. (1979). Às̩àyan Oríkì: Oúnje, Ohun-Ogbin, Eèrà, E̩ye̩, E̩ranko Àti Ejo. Ibadan:

University Press Ltd.

Aremu, P.S.O, Banjo,B.O; et.al. (2012). “Egungun Tradition in Trado-Modern Society

in South-Western Nigeria”. Mediterranean Journal of Social Sciences. Vol. 3 (1) January 2012 ISSN 2039‐2117 (Doi: 10.5901/mjss.2012.03.01.283) (pp. 283-

Babalo̩lá, A. (2001). Àwo̩n Oríkì Orílè̩ Metàdínlógún. Lagos: National Library of

Nigeria Cataloguing in Publicàtion Data.

Biobaku, S.O. (1973). Sources of Yorùbá History. Lo̩ndon: Oxford University Press.

Biodun J. Ogundayo. (2009). “Yoruba” in Encyclopedia of African religions (2nd

Edition),(London: A Sage Reference Publication, 2009)

Daramola, O. Àti Jeje, A. (1975). Àwo̩n Às̩à àti Orísa Ilé Yorùbá. Ibadan: Oníbon-Oje

Press.

Frye et al. (1985) The Harper Handbook to Literature, New York: fé̩Harper & Row,

Publishers.

Fálẹ́yẹ, A. A. (2011a), “Limiting the Dehumanization of Womanhood: An appraisal

Chief (Mrs.) Títí Àtíkù Abubakar’s Contributions In Ìjèsà Icons & The Making

of Modern Nigeria. Oyeweso Siyan. (ed/s.). University Press Plc, Ìbàdàn. Nigeria. (Pp. 221-241).

Fálẹ́yẹ, A. A. (2011b), “Praise Poetry Performance in the Pantheon of Divinities: A

Socio-Semantic and Cultural Interpretations” In Yorùbá, Journal of Yorùbá Studies. Association of Nigeria. Vol. 6, No 1. (pp. 107-138.)

Fálẹ́yẹ, A. A. (2016), “Viewing Oríkì Ọba Okùnadé Àdèlé Síjúwadé Olúbùṣe II

From Socio-cultural and Literary Perspective”. Ifẹ̀ Journal of Languages and

Literatures, Vol. 2, No. 1 (pp. 258-275).

Fálẹ́yẹ, A. A. (2022), “Gendered Species of Yorùbá Plants: An Ecofeminist

Perspective In Yorùbá Studies Review, Vol 8, No (1): (pp. 67-86). University of Texas.

Ilésanmí, T. M. (2009). Àwo̩n Nnkan Abàmì Ilè̩ Yorùbá. Ilé-Ifè̩: O̩báfé̩mi Awólo̩wò̩

University Press Ltd.

Ládélé, T.A.A (2006). Àkójo̩pò̩ Ìwádìí Ìjìnlè̩ Às̩à Yorùbá. Ìbàdàn: Gavima Press Ltd.

O̩dúnjo, J.F. (2018). Aláwìíyé: Iwé Kefa. Lagos: Learn Africa Plc.

Ògúndèjì, P.A. (1991). Introduction to Yorùbá Oral Literature. Ibadan: Centre for External Studies, University of Ìbàdàn.

Olafimihan, J.B. (1953). Àwo̩n È̩dá Alààyè. London: Longman, Green and Co Ltd.

Odeyemi, J.S. (2013) Gender Issues Among the Yorubas in The International Journal of African Catholicism. Winter 2013. Volume 4, Number 1.

Isola, S. I. (2023), “Ìtúpalè̩ Ìpohùn àti Àmì Inú Às̩àyàn Ìbo̩ Èwe ní Ilè̩ Yewa-Àwórì

È̩gbá àti Among Yewa-Àwórì, È̩gbá and Ìjè̩bú)” Unpublished Ph.D Thesis, O̩báfé̩mi Awóló̩wò̩ University, Ilé-Ifè̩.

Audio CD

Fálẹ́yẹ, A. A. (2009), “Ariwo Ayọ̀” Audio CD Album (An Ẹ̀sà.Egúngún and

Àdàmọ̀-Ifẹ̀ Performances mode of Presentation). Composed and Produced by Fálẹ́yẹ A. Adéọlá. Vol. 3. Shalom Studios, Ile-Ifẹ̀: Nigeria.

Fálẹ́yẹ, A. A. (2010a), Ẹ máa tú yagba” Audio CD Album (An Ẹ̀sà Egúngún, and

Àdàmọ̀-Ifẹ̀ Performance modes of Presentation). Composed and produced Fálẹ́yẹ A. Adéọlá in honour of Ọba Okùnadé Ṣíjúwadé Olúbùṣe II, Ọ̀ọ̀ni of Ifẹ̀, on his 80th Anniversary. Vol.4, Shalom Studios, Ilé-Ifẹ̀: Nigeria.

Fálẹ́yẹ, A. A. (2011), “Jẹ́ ká gbáyé pẹ́…” An Audio CD Album (featuring Ẹ̀sà

Egúngún, chanting modes of presentation). Composed and Produced by Fálẹ́yẹ A. Adéọlá. Vol.6. Shalom Studios, Ilé-Ifẹ̀: Nigeria.

Fálẹ́yẹ, A. A. (2016), “Mo Ń Bọ́ba Rèhà…” An Audio CD Album (rendered in

Ẹ̀sà Egúngún chanting mode featuring the Òríkì of the incumbent Ọ̀ọ̀ni Adéyẹyè

Eniìtàn Ògúnwùsì, Ọ̀jájá II lineage, the entire fifty-one royalties crowned in Ifẹ̀, and other seven panegyrics of Yorùbá lineages. Composed and Produced by Fálẹ́yẹ A.

Adéọlá. Vol.7. 101 Audio-visual Studios, Òṣogbo: Nigeria.

Fálẹ́yẹ, A. A. (2018), “Onínúure lo̩” An Audio CD Album (rendered in Èsà

Egúngún chanting mode, in honour of late Prof Akínwùmí Ìsọ̀lá and Ìlọ̀kó lineage. Composed and produced by Fáléye Adijat Adéolá. Vol.9. 101 Audio-visual Studios, Òsogbo: Nigeria.

Fálẹ́yẹ, A. A. (2024) Àkójo̩pọ̀ Ewì Àtinúdá – (In Press).

Internet/Online References

Facebook Source

Ifátó̩la Akínwùmí (2021), The Power of Ifá. Oríkì àwo̩n Ìyà mi Facebook Page. 21 Dec.

Https:// audiomack.asabioje.afenapa.com

Audio-visual CD

Tópé Àlàbí (2005) “Mo rí Ìyanu” Produced by Remdel Optimum Communications, Nigeria.

Tópé Àlàbí (2014) “Orúkọ Tuntun” Produced by Remdel Optimum Communications,

Àkúré, Nigeria.

Sulaimon Ayilara (Ajóbíewé) Oríkì Orílè̩ (1 & 2) – Utube versión (2009).

Published

06-08-2025

How to Cite

FÁLÉ̩YE A. A. . (2025). Ìtúpalè̩ Ìs̩àfihàn Èrò Ìjìnlè̩ nípa Agbára Olódùmarè, Ìsò̩rí Ìs̩è̩dá Abè̩mí, àti Aje̩mé̩ranko nínú Ìlò Oríkì: A Socio-Cultural Analysis of Power of Creator, Creatures, and Animatory Creatures through the use of Oríkì. NJINGA&SEPÉ: evista nternacional e ulturas, Línguas fricanas rasileiras, 5(Especial I), 80–110. etrieved from https://revistas.unilab.edu.br/njingaesape/article/view/2326