Oríkì Gẹ́gẹ́ bí Ìwògbè Aṣàfihàn Iṣẹ́ Akọni: Ìtúpalẹ̀ Ìgbòkègbodò Akinlúùsẹ̀ ní Ìsẹ̀-Èkìtì
A poesia como representação visual da ação heroica: uma análise do desenvolvimento do Akinlùùssè em Issù-Ekiti
Mots-clés :
Akọni, Ìsẹ̀-Èkìtì, Ìtàn, Oríkì, Ifá, Akinlúùsẹ̀Résumé
Iṣẹ́ rẹpẹtẹ ni àwọn onímọ̀ lítíréṣọ̀ Yorùbá ti ṣe lórí oríkì Yorùbá tí í ṣe àká aṣàfihàn àṣà àti ìṣe Yorùbá tí ó tóbi, tí ó sì ṣe pàtàkì jù lọ láàárín àwọn ewì alohùn Yorùbá. Àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ṣe àgbéyẹ̀wò orírun onírúurú ẹ̀yà ìran Yorùbá nínú oríkì-orílẹ̀ wọn. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló ṣe ìtúpalẹ̀ èrò àti ìgbàgbọ́ Yorùbá nínú oríkì. Kódà, ìwádìí ti jinlẹ̀ nípa ipa mánigbàgbé tí ọ̀kan-ò-jọ̀kan akọnikùnrin àti akọnibìnrin kó ní agbègbè ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn àti ilẹ̀ Yorùbá lápapọ̀. Bí ìwádìí ṣe gbòòrò tó nípa oríkì, a kò tí ì ṣe àkíyèsí iṣẹ́ tí ó ṣe ìtúpalẹ̀ tí ó jinlẹ̀ nípa ipa ribiribi tí akọnidòrìṣà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akinlúùsẹ̀, tí a tún mọ̀ sí Akinlúàdusẹ̀ kó ní Ìsẹ̀-Èkìtì. Ìwọ̀-oòrùn Gúsù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ilẹ̀ Yorùbá ni Ìsẹ̀-Èkìtì wà. Iṣẹ́ yìí ṣe ìtúpalẹ̀ oríkì Akinlúùsẹ̀ láti ṣe àfihán agbára akọni yìí, ìhùwàsí ojú-ni-alákàn-fi-ń-ṣọ́rí rẹ̀, oore tí ó ṣe fún àwọn ènìyàn ìlú Ìsẹ̀ àti bí ó ṣe fi ọdún Ọ̀pá lọ́lẹ̀ ní ìlú náà láti lè mú kí ipa rere tí ó kó ní àwùjọ náà di mánigbàgbé àti láti gbin ìgboyà àti ìṣe akin sí gbogbo ọmọ bíbí Ìsẹ̀ lọ́kàn láti ìran kan dé èkejì. Ìlànà ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ni a gùn lé làti ṣe àkójọ èdè fáyẹ̀wò. A fọ̀rọ̀ wá àwọn àgbàlagbà àti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ agbátẹrù àṣà lẹ́nu wò ní ìlú Ìsẹ̀ àti ìlú Osí. Àbájáde ìwádìí yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé oríkì jẹ́ oríṣìí ewì tí ìran Yorùbá ṣe gbogbo nǹkan tó rọ̀ mọ́ ìgbé ayé àti ìgbòkègbodò akọni lọ́jọ̀ sí. Ìlànà ìtúpalẹ̀ afọ̀ ni a mú lò láti ṣe ìtúpalẹ̀ détà. Orí èrò tí iṣẹ́ yìí gúnlẹ̀ sí ni pé oríkì Yorùbá jẹ́ ìwògbè tó ń ṣe àfihàn ìdánimọ̀ akọni àti ìgbòkègbodò rẹ̀ pẹ̀lú ẹwà èdè àti onírúurú ọ̀rọ̀ ayàwòrán.
********
Estudiosos da literatura iorubá têm realizado um trabalho significativo sobre a poesia iorubá — uma grande expressão da cultura e da tradição desse povo e a mais importante entre suas obras poéticas. Tais obras examinam as origens dos diversos grupos étnicos iorubás por meio de sua poesia nacional e analisam o pensamento e as crenças iorubás nela contidos. De fato, pesquisas têm sido conduzidas sobre o papel memorável desempenhado por heróis e heroínas em suas respectivas regiões e em todo o território iorubá. Apesar da extensa pesquisa sobre o tema, não houve, até o momento, nenhum trabalho que analisasse em profundidade a grande influência de um herói chamado Akinluusse — também conhecido como Akinluadusse — na localidade de Isse-Ekiti. Isse-Ekiti situa-se no sudoeste da Nigéria, em território iorubá. Este trabalho analisa a poesia de Akinluusse para destacar o poder desse herói, seus feitos heroicos, a benevolência demonstrada para com o povo de Isse e a forma como celebrou o "Ano do Rato" na cidade, tornando seu impacto positivo na comunidade inesquecível e incutindo coragem e bravura em todos os filhos de Isse, de uma geração para a outra. O método de entrevista foi utilizado para coletar a amostra linguística; entrevistaram-se adultos e jovens que são portadores da cultura nas cidades de Isse e Osi. Os resultados do estudo confirmaram que a poesia iorubá é um gênero utilizado pelo povo para expressar tudo o que se relaciona à vida e às atividades do herói na sociedade. Utilizou-se um método analítico para o tratamento dos dados. A ideia central deste trabalho é que a poesia iorubá expressa a identidade do herói e suas atividades por meio da beleza da linguagem e de diversos recursos de linguagem figurada.
Téléchargements
Références
Abímbọ́lá, W. (1969). Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá – Apá Kejì. Ìbàdàn: Oxford University Press.
Abímbọ́lá, W. (2006). Àwọn Ojú Odù Mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndínlógún. Ìbàdàn: University Press Plc.
Adéẹ̀kọ́, A. (2001). “Oral Poetry and Hegemony: Yorùbá Oríkì.” Dialectical Anthropology. Kluwer Academic Publishers. No. 26. Pp.181-192.
Akinduti, T. O. and Sheba, J. O. (2025). “Motherhood and Infertility as Performance Paradigms of Ọpá Festival.” Yoruba Studies Review. Texas, Florida in U. S. A. and University of Ibadan. Vol. 10, No. 1, Spring, pp. 53-72.
Akinṣọla, I. T. (2025). “Oríkì and trending hype performance in Nigeria: an aesthetics of cultural hybridisation for economic purpose.” Journal of Aesthetics & Culture.Routledge. Vol. 17, No. 1. Pp. 1-12.
Ararọba, T.O. (2019) “Àtúpalẹ̀ Ojú Àmúwayé Yorùbá nínú Lítíréṣọ̀ Ọdún Ọ̀pá ní Ìlú Osí àti Ìpinṣà ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó.” (An Analysis of Yorùbá Worldview of the Orature of Ọ̀pá Festival in Oǹdó State). Unpublished Doctoral Thesis, submitted to the Department of Linguistics and African Languages, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.
Ararọba, T.O. (2018). “The Construction of Oriki in Selected Yoruba Folktales’ Songs.” Akungba Journal of Linguistics and Literatures. No 9. Pp.106-114.
Aruna, J.O. (2022). “Socio-Cultural Impacts of Ogigi Festival among the Ikalẹ People of Ondo State, Nigeria.” Journal of African Studies and Sustainable Development. Vol. 5, No. 2. Pp. 35-46.
Babalọla, A. (1966). The Content and Form of Yorùbá Ìjálá. Oxford: Clarendon Press.
Baber, K. (1991). I Could Speak Until Tomorrow: Oríkì, Women and the Past in a Yoruba Town. Edinburgh: Edinburgh University Press.
Banjo, R. N. (2025). “Yorùbá folklore and mythical metaphors in Kunle Afọlayan’s Citation.” Journal of African Cinemas. Pp. 1-17.
Carter-Ényì, A. (2018). “”Lùlù fún wọn”: Oríkì in Contemporary Culture.” Ethnomusicology. Vol. 62, 1. Pp. 83-103.
Gee, J. P. (2011). An Introduction to Discourse Analysis Discourse Analysis: Theory and Method (3rd ed.). Routledge. https: //doi.org/10.4324/9780203847886
Layẹni, O. (1978). “Ètò ogun jíjà nílẹ̀ Yorùbá.” In Ọlájubù, O. (ed.) Ìwé Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá. Lagos: Longman Nig. Ltd. Pp. 194-202.
Morgan, K. (1988). Legends from Yorubaland. Ibadan: Spectrum Books Ltd.
Ọlatunji, O.O. (2005). Features of Yoruba Oral Poetry. Ìbàdàn: Ìbàdàn University Press Plc. Ltd.
Téléchargements
Publiée
Comment citer
Numéro
Rubrique
Licence
© NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras 2026

Ce travail est disponible sous licence Creative Commons Attribution - Pas d'Utilisation Commerciale - Pas de Modification 4.0 International.
Les auteurs qui publient dans cette revue acceptent les conditions suivantes:
Les auteurs conservent le droit d'auteur et accordent à la revue le droit de première publication, l'œuvre étant simultanément concédée sous licence Creative Commons Attribution License, qui permet le partage de l'œuvre avec reconnaissance de la paternité de l'œuvre et publication initiale dans ce magazine.
Les auteurs sont autorisés à assumer séparément des contrats supplémentaires, pour la distribution non exclusive de la version de l'ouvrage publié dans cette revue (par exemple, publication dans un référentiel institutionnel ou en tant que chapitre de livre), avec reconnaissance de la paternité et publication initiale dans cette revue.
Les auteurs sont autorisés et encouragés à publier et distribuer leurs travaux en ligne (par exemple dans des référentiels institutionnels ou sur leur page personnelle) à tout moment avant ou pendant le processus éditorial, car cela peut générer des changements productifs, ainsi que citation des travaux publiés (voir l'effet du libre accès).