Àfihàn Ohun tí Ifá sọ Nípa Aṣàyàn Ẹranko Láwùjọ Yorùbá
Revelando o que Ifá diz sobre a seleção animal na sociedade iorubá
Résumé
ÀṢAMỌ̀
Pàtàkì ni Ifá jẹ́ lára lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá.Awùjọ Yorùbá sì ní ìgbàgbọ́ púpọ̀ nínú rẹ̀. Kò sí ohun tí Ifá kò sọ̀rọ̀ lé lórí, bẹ̀rẹ̀ láti orí ọmọ ẹ̀dá ènìyàn, ìbáṣepọ̀ láàrin ọkọ àti aya, igi oko, òkè, odò, ilẹ̀, ewéko, ẹyẹ, kòkòrò, ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, ìtàn àwọn òrìṣà àti àwọn ẹranko lóríṣiríṣi. Ifá sọ̀rọ̀ púpọ̀ lórí oríṣiríṣi àwọn ẹranko igbó, gbogbo àwọn ẹranko tí Ifá sọ̀rọ̀ nípa wọn ni ó fi pa òwe fún àwọn ọmọnìyàn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ifá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko tí ó sì fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Bí àpẹẹrẹ wọ́n lè ní ìṣòro kí wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Babaláwo kí wọ́n lọ dífá, kí ìṣòro wọn ó sì jẹ mọ́ ẹbọ rírú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ifá kún fún oríṣiríṣi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Ifá ni ó jẹ́ ká mọ̀ nípa ìtàn ìwásẹ̀ àwọn ẹranko, ó sì tún jẹ́ kí àwọn ọdẹ mọ orúkọ tí à ń pe àwọn ẹranko wọ̀nyí lóríṣiríṣi àti irú ipa tí wọ́n ń kó láwùjọ àwọn ènìyàn. Ohun tí iṣẹ́ yìí tẹpẹlẹ mọ́ jù lọ ni àfihàn ohun tí Ifá sọ nípa àwọn ẹranko. Bí o ṣe fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ọwọ́ Olódùmarè mìíràn láwùjọ. Àwọn ìsọ̀rí tí a gbé yẹ̀wò nínú iṣẹ́ yìí ni ìtàn àwọn ẹranko bí ó ṣe hàn nínú Ifá, àfihàn àwọn ẹranko nípa ìhùwàsí wọn àti ẹ̀kọ́ tí ó kọ́ àwùjọ.
*******
Ifá é uma parte importante da literatura oral iorubá. A sociedade iorubá tem muita fé nele. Não há nada sobre o qual Ifá não fale, começando pelos seres humanos, a relação entre marido e mulher, árvores, montanhas, rios, terra, plantas, pássaros, insetos, a relação com a natureza, as histórias dos deuses e vários animais. Ifá fala muito sobre vários animais selvagens; todos os animais sobre os quais Ifá fala são usados como provérbios para os humanos. Muitas vezes, Ifá fala sobre animais e os apresenta como pessoas. Por exemplo, eles podem ter problemas para ir ao Babalawo para ir ao templo, e seus problemas podem estar relacionados a sacrifícios e assim por diante. Ifá é repleto de vários conhecimentos místicos. Ifá nos conta sobre a história da origem dos animais e também permite que os caçadores conheçam os nomes desses animais e o papel que desempenham na sociedade humana. O que esta obra mais persistentemente faz é apresentar o que Ifá diz sobre os animais. Como os apresenta como outra criação de Deus na sociedade. As categorias examinadas neste trabalho são a história dos animais como retratada em Ifá, a representação dos animais em termos de seu comportamento e as lições que eles ensinam à sociedade.
Téléchargements
Références
Àkọ́jọpọ̀ Ìwé
Abímbọ́lá, W. (1975). Sixteen Great Poems of Ifá. UNESCO.
Abímbọ́lá, W. (1977). Ifa Divination Poetry. London: New York, NOK.
Abímbọ́lá,W.(2004). Àwọn Ojú odù mẹ́rìndínlógún. Ìbàdàn: University Press Plc.
Abímbọ́lá, W. Abímbọ́lá,W(2006). Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá. Apá Kejì. Ìbàdàn: University
Press Plc.
Bascom.W,(1969).Ifá divination &communication between Gods and Men in West
Africa India.University Press,Bloomington.
Eagleton, T. (1983). Literary Theory: An Introduction. New York: Brazil Blackwell
Publishers Ltd.
Agboọlá,F.(1969).Ojúlówó Oríkì Ifá.Apá kìn-ín-ni. Lagos:Project Publication Limited.
Ọlátúnjí, O. (1984). Features of Yorùbá Oral Poetry. Ìbàdàn: University Press Ltd.
Àṣáolú, Y. (1981). Ìwé Ìléwọ́ Ifá Fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́. Iléṣà: Fátírègún Press and
Publishing Co. (Nig) Ltd.
Téléchargements
Publiée
Comment citer
Numéro
Rubrique
Licence
(c) Tous droits réservés NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras 2025

Ce travail est disponible sous licence Creative Commons Attribution - Pas d'Utilisation Commerciale - Pas de Modification 4.0 International.
Les auteurs qui publient dans cette revue acceptent les conditions suivantes:
Les auteurs conservent le droit d'auteur et accordent à la revue le droit de première publication, l'œuvre étant simultanément concédée sous licence Creative Commons Attribution License, qui permet le partage de l'œuvre avec reconnaissance de la paternité de l'œuvre et publication initiale dans ce magazine.
Les auteurs sont autorisés à assumer séparément des contrats supplémentaires, pour la distribution non exclusive de la version de l'ouvrage publié dans cette revue (par exemple, publication dans un référentiel institutionnel ou en tant que chapitre de livre), avec reconnaissance de la paternité et publication initiale dans cette revue.
Les auteurs sont autorisés et encouragés à publier et distribuer leurs travaux en ligne (par exemple dans des référentiels institutionnels ou sur leur page personnelle) à tout moment avant ou pendant le processus éditorial, car cela peut générer des changements productifs, ainsi que citation des travaux publiés (voir l'effet du libre accès).