Ojúṣe èrò ìwòran nínú àgbéjádé lítíréṣọ̀ alohùn yorùbá
O papel da imaginação visual no desenvolvimento da literatura oral iorubá
Mots-clés :
Ojúṣe, Èrò Ìwòran, Lítíréṣò, YorùbáRésumé
ÀṢAMỌ̀
Lítíréṣọ̀ alohùn ilẹ̀ Áfíríkà ti wà kí ètò ẹ̀kọ́ ilé-ìwé tó dé, èyí kò sì yọ àwọn Yorùbá ní Gúsù ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà sílẹ̀. Yorùbá ti ní wọ́n sì tún ní ohun tí a lè pè ní àṣà àti ìsẹ̀ṣe tí a mọ̀ wọ́n mọ̀. Èyí ni a lè pè ní lítíréṣọ̀ tiwọn èyí tí wọn ń tàn ká nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu láti ìran kan sí èkejì tó sì kún ojú òṣùwọ̀n fún lílò láti rí i dájú pé àlàáfíà jọba láàrin wọn àti fún ìdàgbàsókè àwùjọ wọn. Ọ̀kan lára lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá ni ewì alohùn Yorùbá. Apilẹ̀kọ yìí ń ṣàgbéyẹ̀wò iṣẹ́ àwọn akéwì/apohùn, òṣèré, pàápàá jù lọ ipa èrò ìwòran lórí àgbéjáde lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá. Lára èròǹgbà iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ni: láti fi ojú lámèyítọ́ wo ipa àwọn èrò ìwòran nínú gbígbékalẹ̀ lítíréṣọ̀ alohùn; latí wo ànfààní tàbí àlébù ipa tí a ń wí yìí lórí oníṣẹ́ ọnà fúnrarẹ̀, èrò ìwòran àti àwùjọ lápapọ̀; A fi lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá ṣe ìtìsẹ̀ wa. Àwọn iṣé àpilẹ̀kọ díẹ̀ ti wà tí a lè tọ́ka sí lórí kókó ọ̀rọ̀ yìí. Lára wọn ni ti Àkàngbé (2021) àti Akínyẹmí (2012). Àwọn méjèèjì ló sọ̀rọ̀ léréfèé lóri ipa èrò ìwòran nínú àgbéjáde lítíréṣọ̀ àtẹnuwí. Àwọn wọ̀nyí ni a fi ṣe àtẹ̀gùn tí a sì wo orí ọ̀rọ̀ náà ní àwòfín. Aṣèwádìí ṣe àmúlò ọgbọ́n ìwádìí “ṣé kí n rí i” nípa síṣe alábápín ọdún egúngún ní ìlú kan ni ìpínlẹ̀ Kwara, kíkó àwọn ìpéẹ̀rẹ̀ jọ fún eré àlọ́, wíwo eré síṣe lọ́kan-ò-jòkan lórí ìtàgé àti nínú Sinnimọ́. Iṣẹ́ ìwádìí yìí sàmúlò tíọ́rì sosiọ́lọ́jì èyí tó ní ṣe pẹ̀lú ìbágbépọ̀ ara ẹni ní àwùjọ. A lo tíọ́rì yìí ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé asàfihàn àwùjọ ní lítíréṣọ̀. Fún ìdí èyí, a ní èrò láti fihàn pé gbogbo ohun tí òṣèré, akéwì, apohùn ń gbé jádé ní ṣe pẹ̀lú àwùjọ. Àpilẹ̀kọ náà gúnlẹ̀ pé àwọn èrò ìwòran ní ipa pàtàkì láti kó nínú àgbéjáde lítíreṣọ̀ alohùn. Wọ́n ní ipa pàtàkì láti kó nínú àṣeyọrí tàbí ìkùnà akéwì, apohùn tàbí òṣèré. Ìdí nìyí tó fi ṣe pàtàkì láti fi wọ́n sí aàyè tó tọ́ sí wọn. Lára èròǹgbà iṣẹ́ ìwádí yìí ni láti jẹ́ kí a mọ̀ pé kìí ṣe wíwà ní ìkàlẹ̀ èrò ìwòran ló ṣe pàtàkì bí kò ṣe ipa wọn lóri àgbéjádé iṣẹ́ lítíréṣọ̀ alohùn.
*****
A literatura oral africana existia antes do advento do sistema escolar, e isso não excluiu o povo iorubá do sudoeste da Nigéria. Os iorubás têm e ainda têm o que pode ser chamado de seus próprios costumes e práticas. Isso pode ser chamado de sua própria literatura, que eles espalharam por meio da transmissão oral de uma geração para outra e que é suficiente para garantir a paz entre eles e para o desenvolvimento de sua sociedade. Uma das formas de literatura oral iorubá é a poesia oral iorubá. Este artigo examina o trabalho de poetas/narradores, atores e, especialmente, a influência do teatro no desenvolvimento da literatura oral iorubá. Os objetivos deste artigo são: examinar criticamente o papel dos conceitos visuais no desenvolvimento da literatura oral; examinar os benefícios ou desvantagens dessa influência sobre o próprio artista, o conceito visual e a sociedade como um todo; e usar a literatura oral iorubá como ponto de partida. Existem alguns artigos que podem ser citados sobre este tema. Entre eles estão os de Ákangbé (2021) e Akínyêmí (2012). Ambos discutiram brevemente o papel dos conceitos visuais no desenvolvimento da literatura oral. Estes são usados como um trampolim e analisamos o tópico sob uma perspectiva. O pesquisador utilizou o método de pesquisa "deixe-me ver" participando de uma comunidade de 10 anos em uma cidade no estado de Kwara, coletando amostras para uma peça e observando apresentações no palco e no cinema. Este trabalho de pesquisa utilizou a teoria sociológica, que trata da interação social dos indivíduos em sociedade. Essa teoria foi utilizada de acordo com a crença de que a sociedade é um reflexo da literatura. Portanto, pretendemos mostrar que tudo o que um ator, poeta ou escritor produz está relacionado à sociedade. O artigo conclui que as ideias do público desempenham um papel significativo na produção de obras literárias. Elas desempenham um papel significativo no sucesso ou fracasso de um poeta, escritor ou ator. Por isso, é importante dar a elas o devido lugar. Parte do propósito desta pesquisa é nos fazer perceber que não é a presença de ideias visuais que importa, mas sim o seu papel no desenvolvimento de obras literárias.
Téléchargements
Références
Abimbọla, W. (1975). Yorùbá Oral Tradition. Ibadan. University Press.
Abimbọla, W. (1976). Ifá: An Exposition of Ifá Literary Corpus. Ìbàdàn: Oxford University Press.
Abimbọla, W. (1977). Àwọn Ojú Odù Mẹ́rẹ̀ẹ̀rìndínlógún. Ìbàdàn: Oxford University Press.
Abimbọla, W. (2006). Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá - Apá kìnní. Ìbàdàn: University Press Plc.
Abimbọla, W. (1975). Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá - Apá kejì. Ìbàdàn: University Press Plc.
Faniyi, D. (1975). “Ẹkún Ìyàwó: A Yorùbá Nuptial Chant.” In Wande Abimbọla (ed).
Yorùbá Oral Tradition. Ibadan. University Press.
Akangbe, C.A. (2021): The role of the audience in oral performance.
https://scispace.com/papers/the-role-of-the-audience-in-oral-performance-4wjypbl1w4
Akinyẹmi, A. (2012), African Oral Tradirtion, Then and Now: A Culture in transition.
https://scispace.com/papers/african-oral-tradition-then-and-now-a-culture-in-transition-1knnanv1dt
Finnegan, R. (2012). Oral Literature in Africa. Cambridge, Open Book Publisher.
Ogunjimi, B.; Na’Allah, A. (1991). Introduction to African Oral Literature. Ilọrin: Unilọrin Press
Ogunlo̩la, O. D. (2004). “Njé̩ Àgbó̩so̩ ni Ìsàré Yorùbá Bí?” Nínu ALÓRE: Journal of the Humanities. 14. 145-160. Published by Faculty of Arts, University of Ilo̩rin. Unilo̩rin Press.
Ọlatunji, O.O. (1984). Features of Yorùbá Oral Poetry. Ibadan: University Press Plc.
Téléchargements
Publiée
Comment citer
Numéro
Rubrique
Licence
(c) Tous droits réservés NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras 2025

Ce travail est disponible sous licence Creative Commons Attribution - Pas d'Utilisation Commerciale - Pas de Modification 4.0 International.
Les auteurs qui publient dans cette revue acceptent les conditions suivantes:
Les auteurs conservent le droit d'auteur et accordent à la revue le droit de première publication, l'œuvre étant simultanément concédée sous licence Creative Commons Attribution License, qui permet le partage de l'œuvre avec reconnaissance de la paternité de l'œuvre et publication initiale dans ce magazine.
Les auteurs sont autorisés à assumer séparément des contrats supplémentaires, pour la distribution non exclusive de la version de l'ouvrage publié dans cette revue (par exemple, publication dans un référentiel institutionnel ou en tant que chapitre de livre), avec reconnaissance de la paternité et publication initiale dans cette revue.
Les auteurs sont autorisés et encouragés à publier et distribuer leurs travaux en ligne (par exemple dans des référentiels institutionnels ou sur leur page personnelle) à tout moment avant ou pendant le processus éditorial, car cela peut générer des changements productifs, ainsi que citation des travaux publiés (voir l'effet du libre accès).