Orin Kúlúńbú: Ọnà Ìfiniṣẹ̀fẹ̀ àti Ìjánu Àwùjọ ní Ìlú Ọjà-Ọ̀dàn Yewa
Resumen
Ṣaájú kí àwọn Òyìnbó tó dé ilẹ̀ Adúláwọ̀ pàápàá ilẹ̀ Yorùbá, onírúurú isẹ́-ọnà ajẹmọ́-ìpohùn ni ó wà ní agbègbè kọ̀ọ̀kan tí wọ́n sì máa ń wà bí ohun ìdámọ̀ fún agbègbè tí wọ́n bá ti ń lò wọ́n. Ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́-ọnà ajemọ́-ìpohùn yìí ni orin jẹ́ láàárín àwọn ẹ̀yà Yorùbá, ó sì wà fún ìnàjú, ìdánilárayá àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Èyí ni ó máa ń mú kí àwùjọ àwọn Yorùbá ní ìfẹ́ sí orin kíkọ níbikíbi, nígbàkúùgbà àti lórí ohunkóhun. Ọ̀kan nínú àwọn orin ìbílẹ̀ Yorùbá tí ó gbajúmọ̀ láàárín àwọn ènìyàn ìlú Ọ̀jà-Ọ̀dàn ni orin Kúlúḿbú tí ó jẹ orin ajemọ́-eré-oníṣe, tí ó sì tún jẹ mọ́ ìfiniṣẹ̀fẹ̀. Ìlépa iṣẹ́ yìí ni láti ṣe àfihàn orin Kúlúńbú ní ìlú Ọjà-Ọ̀dàn gẹ́gẹ́ bí ọnà ìṣèré ìpohùn Yorùbá, kí a ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn àkóónú rẹ̀, kí á sì tọ́ka sí àwọn irúfẹ́ ọnà ìfiniṣẹ̀fẹ̀ inú orin yìí pẹ̀lú ọ̀nà tí ó ń gbà fọ àwùjọ mọ́. A ṣe àkójọ àwọn orin Kúlúḿbú tí a lò ní ìlú Ọ̀jà-Ọ̀dàn ní agbègbè Yewa ní ìpínlè Ogun ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. A ṣe òfintótó ìṣèré orin yìí, a sì kópa nínú ìgbékalẹ̀ orin náà. A ṣe àfàyọ àwọn àbùdá eré-oníṣe àti ọnà ìfiniṣẹ̀fẹ̀ tí ó ń jẹ yọ nínú àgbékalẹ̀ orin Kúlúḿbú àti ipa rẹ̀ lórí àwọn ènìyàn àwùjọ. Iṣẹ́ yìí ṣe àfihàn àwọn ẹ̀yà Yorùbá Yewa gẹ́gẹ́ bí alárògún àti oníṣẹ́-ọnà ajẹmọ́-ìpohùn, ó sì tọ́ka sí bí wọ́n ṣe ń lo orin Kúlúńbú fún ìtọ́sọ́nà ètò ìgbé-ayé wọn, ọ̀nà ìjánu àwùjọ àti fún ìdàgbàsókè àwùjọ wọn. Iṣẹ́ yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, iṣẹ́-ọnà láàárín àwọn Yorùbá ń dàgbà sókè lójoojúmọ́ àti pé ìyípadà ọ̀tun ni orin Kúlúḿbú ń mú bá agbègbè tí ó ti ń wáyé. Èyí ni ó sì yẹ kí ó jẹ́ àwòkọ́ṣe fún àwọn oníṣé-ọnà káàkiri ilẹ̀ Yorùbá àti gbogbo àgbáyé.
Descargas
Citas
Abímbọ́lá, W. (1977a) The Study of Yorùbá Literature: An Assesment An Inaugural lecture Delivered at the University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀, Ifẹ̀, University of Ifẹ̀ Press.
Aṣíwájú, A.I. (1976) “Gẹ̀lẹ̀dẹ́ Songs as Source of Western Yorùbá History”. Yorùbá Oral Tradition, Wándé Abímbọ́lá (ed.) Department of African Languages and Literature, University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀: 98-105. Mimeograph.
Awóbùlúyì, O. (1983) (ol.), Yorùbá Meta Language. Ìbàdàn: U.P.L.
Awobuluyi, O. (1990) Yorùbá Metalanguage. Vol. II. Ìbàdàn: University Press
Beier, Ulli and Gbadamọsi, B. (1959) Yorùbá Poetry. Ìbàdàn: Government Printers.
Church Missionary Society (1913) A Dictionary of the Yorùbá Language, Oxford: University Press Plc.
Olúkòjú, E.O. (1985) “Music in Religious Worship” ORITA: a journal of Religious Studies Association of Nigeria, University of Ìbàdàn, Ìbàdàn: 118.
Olúkòjú, E.O. (1994) The Study of Yorùbá Songs. Ìbàdàn, Centre for External Studies. Ìbàdàn: Faculty of Education, University of Ìbàdàn.
Orímóògùnjẹ́ (1999) Lítíréṣọ̀ Alohùn Yorùbá Lagos, Káróhunwí Nig. Entprises.
Rájí, S.M (2008) “Àgbéyẹ̀wò Ajẹmọ́-kókó Ọ̀rọ̀ àti Ìṣọ́wọ́lò-Èdè nínú Ìjálá Àbàbí Ògúndépò”. Unpublished M.A Dissertation, Department of Linguistics and African Lan guages, O.A.U, Ilé-Ifẹ̀.
Rájí, S.M. (2014) “Àgbéyẹ̀wò Ojú Àmúwayé àti Lítíréṣọ̀ Alohùn Yorùbá nínú Orin Musulumi ní Ilẹ̀ Yorùbá.” Unpublished PhD Thesis Department of Linguistics and African Languages O.A.U, Ilé-Ifẹ̀.
Descargas
Publicado
Cómo citar
Número
Sección
Licencia
Derechos de autor 2025 NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras

Esta obra está bajo una licencia internacional Creative Commons Atribución-NoComercial-SinDerivadas 4.0.
Los autores que publican en esta revista aceptan los siguientes términos:
Los autores mantienen los derechos de autor y otorgan a la revista el derecho a la primera publicación, siendo el trabajo simultáneamente licenciado bajo la Licencia de Atribución Creative Commons, que permite compartir el trabajo con reconocimiento de la autoría del trabajo y la publicación inicial en esta revista.
Se autoriza a los autores a asumir contratos adicionales por separado, para la distribución no exclusiva de la versión del trabajo publicado en esta revista (p. Ej., Publicación en repositorio institucional o como capítulo de libro), con reconocimiento de autoría y publicación inicial en esta revista.
Se permite y se anima a los autores a publicar y distribuir su trabajo en línea (por ejemplo, en repositorios institucionales o en su página personal) en cualquier momento antes o durante el proceso editorial, ya que esto puede generar cambios productivos, así como aumentar el impacto y cita del trabajo publicado (Ver El efecto del acceso abierto).