Ìdálùú Nìṣèlú: Láríjà Àkóónú Ọdún Ìbílẹ̀ Ọ̀pá ní Ìlú Osí àti Ìlú Ìpinṣà
Controvérsia política: o conteúdo do Ano Tradicional do Cachorro nas cidades de Osi e Ipinsha
Palabras clave:
Ọdún Ìbílẹ̀, Yorùbá, Akinlúùsẹ̀, OsíResumen
ÀṢAMỌ̀
Ìwádìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọdún Ọ̀pá gbéra sọ ní ìlú Osí tí ó wà ní ìhà àríwá Àkúrẹ́ ní ọdún 1419, kò sẹ́ni tó lè fi ìdí déètì pàtó tí ọdún náà bẹ̀rẹ̀ múlẹ̀. Orúkọ akọnikùnrin tí wọ́n ń fi ọdún Ọ̀pá bọlá fún ní ìlú Osí ni Akinlúùsẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ ọ́n sí Òrìṣà-Akin. Akọnibìnrin ni àwọn ará Ìpinṣà tí wọ́n ń gbé ní ìhà Gúsù Àkúrẹ́ ń bọlá fún ní tiwọn, orúkọ rẹ̀ ni Èyé-Mọ̀é. Àwọn akọni wọ̀nyí ni àwùjọ méjèèjì sọ di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ nítorí ipa mánigbàgbé tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kó ní àwùjọ rẹ̀. Ẹgbàágbèje iṣẹ́ ni àwọn onímọ̀ ti ṣe lórí onírúurú ọdún ìbílẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n iṣẹ́ kò tíì dunlẹ̀ lórí ìjọra àti ìyàtọ̀ tó hànde nípa àwọn ìgbésẹ̀, tó fi mọ́ ìpohùn tó ń wáyé nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ọdún Ọ̀pá ní Osí àti Ìpinṣà. Pẹ̀lú àmúlò tíọ́rì Ìfojú-àṣà-ìbílẹ̀-wò, iṣẹ́ yìí gùn lé ọ̀rínkínniwín ìtọpinpin nípa àwọn ìlànà à-ń-tẹ̀lé tó forímù sínú ọdún kọ̀ọ̀kan, ó ṣe àyẹ̀wò láríjà onírúurú ìgbòkègbodò tó rọ̀ mọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, pàápàá jù lọ, ìtọ́ka sí ohun tí ó wọ̀ ní ìlú kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò wọ̀ ní ìlú kejì, ó sì jíròrò lórí àwọn àkóónú tó pa ọdún méjèèjì pọ̀ àti àwọn tó yà wọ́n sọ́tọ̀. Ọgbọ́n ìṣèwádìí tí a gùnlé ni pé, a kópa nínú ọdún náà, a sì gba détà nípasẹ̀ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. Orí èrò tí ìwádìí yìí gúnlẹ̀ sí ni pé bí ìlú méjì bá bá ara wọn tan, tí wọ́n bá sì ń ṣe ọdún tó ń jẹ́ orúkọ kan náà ní oṣù kan náà lọ́dọọdún, síbẹ̀ èrò ìran Yorùbá tó sọ pé, ‘báyìí là ń ṣe nílẹ̀ yìí, èèwọ̀ ni ní ilẹ̀ ibòmíràn,’ kò níí ṣàìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin sínú ìgbòkègbodò ọdún tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń ṣe.
*****
Pesquisas estabeleceram que o ano de Opa começou na cidade de Osi, localizada ao norte de Akure, no ano de 1419, embora ninguém possa confirmar a data exata de seu início. O nome do herói homenageado com o ano de Opa na cidade de Osi é Akinlùùssè, conhecido por muitos como Orììa-Akin. O povo Ipinsha, que vive ao sul de Akure, homenageia uma heroína, cujo nome é Èyé-Mòé. Esses heróis foram transformados em divindades por ambos os grupos devido ao papel inesquecível que cada um deles desempenhou em sua comunidade. Estudiosos têm trabalhado extensivamente sobre os vários festivais tradicionais iorubás, mas pouco se tem feito sobre as semelhanças e diferenças que emergem dos rituais, incluindo os rituais que ocorrem durante a celebração do festival de Opa em Osi e Ipinsha. Utilizando a teoria da perspectiva cultural, este trabalho amplia o escopo do estudo dos rituais que moldam cada festival, examina a interação das diversas atividades associadas a cada um e, em particular, discute as semelhanças e diferenças entre os dois festivais. A metodologia de pesquisa utilizada foi a participação no ano e a coleta de dados por meio de entrevistas. A premissa desta pesquisa é que, se duas cidades estão relacionadas e celebram um ano com o mesmo nome no mesmo mês todos os anos, a crença iorubá de que "é assim que fazemos neste
Descargas
Citas
Ìwé Ìtọ́kasí
Adebua, B.O. and Sotunsa, M.E. (2018). “Dialectics and Structural Organization in Ẹ̀bìbì Festival Performances of the Ẹ̀pẹ́ People in Lagos State, Nigeria.” Yorùbá Studies Review. Vol.2, No. 2. Pp. 199-213.
Ararọba, T. O. (2019) “Àtúpalẹ̀ Ojú Àmúwayé Yorùbá nínú Lítíréṣọ̀ Ọdún Ọ̀pá ní Ìlú Osí àti Ìpinṣà ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó.” (An Analysis of Yorùbá Worldview of the Orature of Ọ̀pá Festival in Oǹdó State). Unpublished Doctoral Thesis, submitted to the Department of Linguistics and African Languages, Ọbafẹmi Awolọwọ University, Ile-Ifẹ.
Fakayọde, F.F. (2011). ÌWÚRE, Efficacious Prayer to OLÓDÙMARÈ, The Supreme Force. Ibadan: Ejiodi Home of Tradition.
Ibrahim, D. (2020). “Women in Yorùbá and Hausa Folktales.” Ifẹ Journal of Languages and Literatures. Vol. 6, No 1. Pp. 102-118.
Logan, P.M. (2012). “On Culture: Matthew Arnold’s Culture and Anarchy 1869” in Felluga, D.F. (ed.) Representation and Nineteenth Century History. New York. http: //www.branchcollective.org>ps_articles= . . . retrieved on March 18, 2025.
Obamwonyi, A.A. and Onyekuru, J.A. (2024). “The Role of Traditional African Festivals in the Sustenance of the Ecosystem: Ikenge Festival in Utagba-Uno, Southern Nigeria as a Paradigm.” Rupkatha Journal on Interdisciplinary Studies in Humanities. Vol. 16, No 1. Pp. 1-17.
Ojo, I.F. (2021). “Representation of Women Power in Gẹ̀lẹ̀dẹ́ Ritual Performance in Yorùbá Culture.” Yorùbá- The Journal of Yorùbá Studies Association of Nigeria.Vol. 10, No. 4. Pp. 101-124.
Omigbule, M.B. (2018). “Portraits of Arenas and Contexts of Understanding of Selected Ritual Performances in Ile-Ifẹ.” Ifẹ: Journal of the Institute of Cultural Studies. Vol. 13. Pp. 38-68.
Ossai-Uloku, C.F. and Anyawu, C. (2024). “Traditional African Festival: Elements and Properties in Akashiede Kingdom’s Ikenge Festival in Ukwuani Local Government Area, Delta State.” International Journal of Latest Research in Humanities and Social Sciences. Vol. 7, Issue 5. Pp. 183-190.
Ọladiran, M.A. (2020). “Orò Pípè; Ètùtù Àtẹnuṣe nínú Ọdún Orò ní Ògbómọ̀ṣọ́.”Yorùbá – Journal of Yorùbá Studies Association of Nigeria. Vol. 10,No. 2. Pp. 61-75.
Ọpẹfeyitimi, J.A. (2014). Tíọ́rì àti Ìṣọwọ́lo-èdè. Ile-Ifẹ: Ọbafẹmi Awolọwọ University Press.
Umejei, A.L. (2023). “Diaspora reconnection with homeland religion, cultural and heritage festival celebration.” Pharos Journal of Theology online. Vol. 104, Issue1. Pp. 1-15.
Descargas
Publicado
Cómo citar
Número
Sección
Licencia
Derechos de autor 2025 NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras

Esta obra está bajo una licencia internacional Creative Commons Atribución-NoComercial-SinDerivadas 4.0.
Los autores que publican en esta revista aceptan los siguientes términos:
Los autores mantienen los derechos de autor y otorgan a la revista el derecho a la primera publicación, siendo el trabajo simultáneamente licenciado bajo la Licencia de Atribución Creative Commons, que permite compartir el trabajo con reconocimiento de la autoría del trabajo y la publicación inicial en esta revista.
Se autoriza a los autores a asumir contratos adicionales por separado, para la distribución no exclusiva de la versión del trabajo publicado en esta revista (p. Ej., Publicación en repositorio institucional o como capítulo de libro), con reconocimiento de autoría y publicación inicial en esta revista.
Se permite y se anima a los autores a publicar y distribuir su trabajo en línea (por ejemplo, en repositorios institucionales o en su página personal) en cualquier momento antes o durante el proceso editorial, ya que esto puede generar cambios productivos, así como aumentar el impacto y cita del trabajo publicado (Ver El efecto del acceso abierto).