Ìpera-ẹni-níjà nínú Ìṣeré Orin Agbè

Self-Defense in the Music of the Tribe

Autores/as

Palabras clave:

Ìpera-Ẹni-Níjà, Kóríyá, Ìṣeré Orin Agbè, Orin Ogun, Tíọ́rì Ìlò-Àmì Nínú Ewì

Resumen

ÀṢAMỌ̀

Ọ̀kan nínú orin kóríyá láàárín àwọn Yorùbá Ọ̀yọ́ ni orin agbè jẹ́. Orin agbè jẹ́ orin ogun, a sì máa ń kọ ọ́ ní ààfìn àwọn Ọba Ọ̀yọ́, àgbàlá àwọn jagunjagun àti ibi ayẹyẹ lóríṣiríṣi. Torí pé orin agbè jẹ mọ́ agbaja ṣíṣe púpọ̀, àwọn òṣèré rẹ̀ máa ń pe ara wọn níjà kí adùn eré náà le hànde. Ìwádìí yìí yàn láti ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí àwọn ọ̀kọrin agbè máa ń gbà pe ara wọn níjà lásìkò eré. Tíọ́rì ìlò-àmì nínú ewì ti Riffaterre (1978) ni a ṣe àmúlò fún àtúpalẹ̀ détà. Àwọn ìṣeré orin agbè tí a gbà sílẹ̀ ni détà àtúpalẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí. A ṣe àmúlò àwọn ọnà-ẹnu Yorùbá mìíràn láti ṣe àlàyé détà iṣẹ́-ìwádìí yìí jìnlẹ̀. Àbájáde ìwádìí fi hàn pé àwọn òṣèré orin agbè máa ń pe ara wọn níjà nínú agbè lílù, orin kíkọ, ìṣeré ojúlówó, ijó jíjó/òkìtì títa/idán pípa fún ìdárayá, níní ìgboyà àti àmúlò òògùn ìkà fún ogun jíjà. Ìwádìí tún fi hàn pé ìpèra-ẹni-níjà àti kóríyá gan-an ni kókó pàtàkì tó ṣe okùnfà ìgbéǹde ìṣeré orin agbè. Ìdí sì nìyí tó fi jẹ́ pé láàárín àwọn jagunjagun Ọ̀yọ́ Ilé ni orin náà ti bẹ̀rẹ̀. Iṣẹ́ yìí tún fi hàn pé ìṣeré orin agbè jẹ́ ọ̀nà-ìdẹ́rùbọ́tá lójú ogun. Ìwádìí jẹ́ ká mọ̀ pé lára ìdí tí orin agbè kò ṣe tí ì parẹ́ di àsìkò yìí ni pé ó jẹ́ orin agbaja fún àwọn ènìyàn Ilé Gbọ̀ńkáà ní Igbó-Ọrà, Ìbàràpá àti pé ó jẹ́ orin ọba Onímia, Ìmià Òkè-Ògùn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

******

Orin agbè is one of the songs of stimulation among the Yorùbá people of Ọ̀yọ́. It is a war song, also sung at the palace of the kings of Ọ̀yọ́, compounds of warlords and social ceremonies. Because orin agbè is full of stimulation, its performers challenge one another to realise the full aesthetics of the song. This study appraises how the performers of orin agbè challenge one another during its performance. Riffaterre’s (1978) semiotics of poetry is employed for data analysis. The study's primary data are the recorded videos of the performances of orin agbè. Some other Yorùbá oral genres are employed for critical analysis of research data. The study reveals that the performers of orin agbè challenge one another in agbè instrumentation, song rendition, quality performance, dance styles/acrobatic and magical displays for entertainment, courageous stimulation and use of baleful charms at battle-field. The study also reveals that challenging and stimulating one another are the main reasons behind the performance of orin agbè. That is the reason the song was originated among the Old Ọ̀yọ́ warlords. It is also revealed in the study that orin agbè is a way of scaring enemies at battle-field. The study explicates that among the factors that have contributed to the sustenance of orin agbè is its use as a song of amusement among the people of Gbọ̀ńkáà’s household at Igbó-Ọrà, Ìbàràpá and also the song of the King Onímià, Ìmià town in Òkè-Ògùn, Ọ̀yọ́ State, Nigeria.

Descargas

Los datos de descargas todavía no están disponibles.

Citas

Ìwé Ìtọ́kasí

Àlàbá I. O. (1985). A socio-stylistic analysis of Orin Agbè: A multimodal genre of Yorùbá oral poetry, àpilẹ̀kọ fún òyè Ph.D, Department of African Languages and Literatures, Faculty of Arts, University of Lagos.

Cobley, P. and Jansz, L. (1999). Introducing semiotics. United Kingdom: Icon Books.

Eco, U. (1976). A theory of semiotics. U.S.A: Indiana University Press.

Kíaríbẹ̀ẹ́, L. A. (2021). Ewì gẹ́gẹ́ bí Ètè Ogun Jíjà Láwùjọ Yorùbá, Yorùbá Studies Review, Falola Toyin, Akintunde Akinyemi and Adejumo Arinpe (Eds), vol. 6. No. 1. Spring 2021, pp. 73-90. Texas, Florida in U.S.A. and Ìbàdàn, Nigeria.

____________ (2022a). Social Status of Agbè and Kete: A Historical and Functional Yorùbá Oral Literary Perspectives, Notion: Journal of Linguistics, Literature and Culture, vol. 4(2), 76-84.

___________ (2022b). Àgbéyẹ̀wò Pípe Àkíyèsí Àwùjọ sí Ìlera wọn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń Jẹyọ nínú Orin Ìbejì àti Orin Ẹgbẹ, Yorùbá: Journal of Yorùbá Studies Association of Nigeria, Olumuyiwa, T. (ed.), vol. 10. No. 2, 41-54.

__________ (2023). A comparative performance semiotics of Orin Kete and Orin Agbè among the Ìbàràpá and Òkè-Ògùn people of Yorùbá, Nigeria, àpilẹ̀kọ fún òyè Ph.D, Department of Linguistics and African Languages, Univerisity of Ibadan.

Ògúndèjì, P.A. (1988). Semiotic study of Duro Ladipọ’s mythico-historical plays, àpilẹ̀kọ fún òyè Ph.D, Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan, Nigeria.

____________ (1991). Introduction to Yorùbá oral literature. Ibadan: University of Ibadan Centre for External Studies.

Ọlátẹ́jú, M. O. A. (1998). A syntactic approach to literary discourse analysis: The Yorùbá example, àpilẹ̀kọ fún òyè Ph.D, Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan, Ibadan.

Ọlátúnjí, O.O. (1984). Features of Yorùbá oral poetry. Ibadan: University Press PLC.

Olúkòjú, E. O. (1978). The place of chant in Yorùbá traditional oral literature, àpilẹ̀kọ fún òyè Ph.D, Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan, Ibadan.

____________ (1985). Some features of Yorùbá songs, West African Languages, Williamson, K. (ed), No. 38, 251-263.

Ọ̀pádọ̀tun, Ọ. (2002). Okòó ewì alohùn. Ọ̀yọ́: Odumatt Press & Publishers.

Ọ̀pádọ̀tun, Ọ., Gbénró, D. and Ọmọ́làsóyè, A. (2005). Ewì alohùn Yorùbá pẹ̀lú fọ́nrán onífídíò: Apá kìn-ín-ní. Ọ̀yọ́: ODUMATT Press and Publishers.

Raji, S. M., Adéọlá, J. O., Òjó, I. F., Táíwò, S. A. and Àjùwọ̀n. (2009). Ọ̀kan-ò-jọ̀kan-ewì alohùn Yorùbá. Ìbàdàn: Amazing Grace Computer.

Sebeok, T. A. (2001). An introduction to semiotic: Second edition. Toronto: University of Toronto.

Publicado

06-08-2025

Cómo citar

KÍARÍBẸ̀Ẹ́ L. A. . . (2025). Ìpera-ẹni-níjà nínú Ìṣeré Orin Agbè : Self-Defense in the Music of the Tribe . NJINGA&SEPÉ: evista nternacional e ulturas, Línguas fricanas rasileiras, 5(Especial I), 172–187. ecuperado a partir de https://revistas.unilab.edu.br/njingaesape/article/view/2331