Ewì Alohùn Nínú Lítírés̩ò̩ Àpilè̩ko̩ Yorùbá: Ìwé Eré-onítàn O̩mo̩ Aláte̩ Ìlè̩kè̩ tí Láwuyì Ògúnniran ko̩ bí Àpe̩e̩re̩

Poemas na literatura iorubá: A história do filho do profeta, de Lawuyì Ógúnnirán

Autores/as

Palabras clave:

Oriki, Litireso, Ede Yoruba

Resumen

ÀS̩AMÒ̩ (Yoruba)

Àwo̩n onímò̩ tíó̩rì ìje̩mó̩pò̩ às̩à ti fidì rè̩ múlè̩ pé kò sí àwùjo̩ tí kò ní às̩à tirè̩, bé̩è̩ ni káríayé bí as̩o̩ onís̩úgà ni ìs̩è̩s̩e jé̩ sí gbogbo orílè̩-èdè ayé. Kò síbi tí a kì í gbé dáná alé̩, o̩bè̩ lè dùn jura wo̩n lo̩.  Inú às̩à lá sì ti fa lítírés̩ò̩ jade fún àǹfààní àti ìgbádùn àwo̩n ènìyàn àwùjo̩ tí ó ni às̩à náà.  Ò̩nà méjì à ń gbà gbé lítírés̩ò̩ jade lágbàáyé, a lè so̩ lé̩nu, kí ó jé̩ eré e̩nu, ó sì lè jé̩ àpilè̩ko̩. Èyí tí a ń so̩ lé̩nu ló wó̩pò̩ jù ní ilè̩ Afirika.  Òun ni à pè ní lítírés̩ò̩ alohùn lóde-òní dípò lítírés̩ò̩ àte̩nudé̩nu tàbí àbáláyé tí à ń pè é té̩lè̩. Púpò̩ nínú àwo̩n onímò̩ is̩é̩ lámèyító̩ ló ti wo ipò àti ipa tí ewì alohùn Yorùbá ń kó nínú lítírés̩o̩ àpilè̩ko̩ Yorùbá àti ìje̩yo̩ rè̩ nínú ìwé èré-onítàn s̩ùgbó̩n abala tí a wò ló jé̩ tuntun èyí ni ìs̩àmúlò ewì alohùn nínú ìwé eré-onítàn aje̩mó̩ ìmò̩-ìtàn O̩mo̩ Aláte̩ Ìlè̩kè̩ tí Láwuyì Ògúnniran ko̩. Àwo̩n onís̩é̩ lámèyító̩ kò tíì fi bé̩è̩ wo ipò àti ipa tí ewì alohùn kó nínú eré yìí bí wó̩n s̩e wo àwo̩n ìwé eré-onítàn aje̩mó̩ ìmò̩-ìtàn yòókù. Nítorí náà, èròǹgbà wa ni láti s̩e àgbéyè̩wò ìs̩àmúlò ewì alohùn nínú eré náà. O̩gbó̩n ìs̩èwádìí tí a lò ni agbàlàyé (Descriptive method), a dìídì yan ìwé eré-onítàn O̩mo̩ Aláte̩ Ìlè̩kè̩ láàárín àwo̩n eré aje̩mó̩ ìmò̩-ìtàn nítórí pé is̩é̩ lámèyító̩ kò tíí pò̩ lórí rè̩. A s̩e àmúlò tíó̩rì aje̩mó̩ ìmò̩-ìtàn nítorí ìtàn ìs̩è̩dálè̩ ilè̩ Yorùbá tó kún fún ìjìnlè̩ ohùn e̩nu Yorùbá ni, ó sì dálé ìtàn ogun. Àbò̩ ìwádìí fihàn pé bí àmù omi ńlá ni ewì alohùn Yorùbá jé̩ fún eré-onítàn àpilè̩ko̩, èyí tí àwo̩n òǹkò̩wé òde-òní ti ń bù mu, tí wó̩n sì ń bù wè̩ bí ó tilè̩ jé̩ pé wó̩n ń dárà sí is̩àmúlò rè̩; a rí ìje̩yo̩ òwe, oríkì, àwís̩e̩ bí o̩fò̩, àásán, ayájó̩, èpè àti orin nínú ìgbékalè̩ àti àhunpò̩ ìtàn, ibùdó eré, ìfìwàwè̩dá, ìlò èdè, kókó-ò̩rò̩. Ìkádìí rè̩ ni pé òpìtàn pàtàkì ni Alàgbà Láwuyì Ogunniran, akéwì ìsè̩ǹbáyé tó jinlè̩ nínú ewì alohùn Yorùbá ni, ó sì fi ìwé O̩mo̩ Aláte̩ Ìlè̩kè̩ pàrokò sí ìran Yorùbá pé kí wó̩n jáwó̩ lápò̩n tí ò yò̩, kí wó̩n gbómi ilá kaná, kí wó̩n wà ní ìré̩pò̩ láìjà mó̩, kí ò̩mo̩ aláte̩ ìlè̩kè̩ má bàá do̩mo̩ aláte̩ ò̩rúnlá àti pé kí ewì àlohùn Yorùbá ó wà títí láé fún ìran tó ń bò̩ lé̩yìn.  

****

Os estudiosos da linguística confirmaram que não existe sociedade que não tenha sua própria língua e, no mundo, como língua comum, ela é usada por todas as nações. Não há lugar onde não vivamos e possamos apreciá-la. E a literatura tem sido produzida a partir da língua para o benefício e o prazer das pessoas da sociedade que a possui. Há duas maneiras pelas quais a literatura é transmitida ao mundo: ela pode ser falada, como forma de entretenimento, e pode ser usada como ferramenta. A língua falada é a mais comum na África. É chamada de literatura oral moderna, em vez de literatura oral ou literária, como era chamada anteriormente. Muitos estudiosos examinaram o papel e o lugar da poesia oral iorubá na tradição literária iorubá e seu uso na ficção histórica, mas o aspecto que estamos examinando é novo, ou seja, o uso da poesia oral no romance de ficção histórica Omo Aláte Îleke, escrito por Lawuyì Ògúnnirán. O papel e a função da poética nesta peça não foram examinados por estudiosos como em outros dramas históricos. Portanto, nosso objetivo é examinar o uso da poética na peça. O método de pesquisa utilizado é descritivo, e escolhemos especificamente a peça Omo Aláte Îleke entre os dramas históricos porque não há muitos trabalhos acadêmicos sobre ela. A teoria da ficção histórica é usada porque a história da nação iorubá é repleta da profundidade da língua iorubá e é baseada na história da guerra. Pesquisas mostram que a poesia iorubá é como um grande reservatório para o drama histórico, que os escritores modernos têm bebido e ainda bebem, embora sejam bons em seu uso; vemos o uso de provérbios, poesia, provérbios como ofo, àasan, ayájo, épe e canção no desenvolvimento e desenvolvimento da história, o cenário do drama, a criatividade, o uso da linguagem, o tema. Sua conclusão é que o Ancião Lawuyì Ogunniran é um grande historiador, um poeta profundamente enraizado na poesia iorubá, e ele escreveu o livro O̩mo̩ Aláte̩ Île̩ke̩, no qual ele exortava a geração iorubá a se libertar do mal, a se libertar do mal, a se libertar do mal, para que o mal do passado não seja esquecido e que a poesia iorubá permaneça para sempre para as gerações futuras.

Descargas

Los datos de descargas todavía no están disponibles.

Citas

Adebisi, A. (2001), Lítírés̩ò̩ alohùn àti o̩gbó̩n ìkó̩ni, Jó̩nà E̩gbé̩ Akó̩mo̩lédè àti As̩à,

Ilè̩ Nàìjíríà, 3 (1),60-68.

Adejumo̩, A. (2011). Text and inter-textuality in contemporary Yorùbá literary works.

In Toyin Falo̩la and Adebayo Oyebade (eds). Yorùbá fiction, orature and

culture, Oyekan Owomoyela and African literature and the Yorùbá experience.

New Jersey: Africa World Press,209-222.

Adeniji, A.A. (1982). O̩fò̩ rere. Ibadan: University Press.

Adeyemi, L. (2011). Politics and proverbs in selected Yorùbá novels. In Toyin Falo̩la

and Adebayo Oyebade (eds). Yorùbá fiction, orature and culture, Oyekan

Owomoyela and African literature and the Yorùbá experience. New Jersey:

Africa World Press, 183-208

Adeyemi, L. (2001). The oratory style of Lawuyi Ogunniran in O̩mo̩ Alate̩ Ìlè̩kè̩ . In

Yorùbá: A journal of the Yorùbá Studies Association of Nigeria 2 (1), 73-89.

Akínye̩mi, A. (2011). Nigerian contemporary dramatists and the art of court praise

singing. In Toyin Falo̩la and Adebayo Oyebade (eds). Yorùbá fiction, orature

and culture, Oyekan Owomoyela and African literature and the Yorùbá experience. New Jersey: Africa World Press,3-26.

Arohunmo̩las̩e̩, O. (2001). Lítírés̩ò̩ alohùn àti ètò ìs̩èlú: Ìlò lítírés̩ò̩ alohùn nínú àwo̩n

eré-onítàn kan bí àpe̩e̩re̩. Jó̩nà E̩gbé̩ Akó̩mo̩lédè àti Àsà Yorùbá, ilè̩ Nàìjíríà, 3

(1),37-44.

Bámgbóṣé, A. (1974). The novels of D.O. Fágúnwà. Benin: Ethiope

Publishing Corporation.

Bámgbóṣé, A. (2007). The novels of D.O. Fágúnwà: A commentary. Ìbàdàn:

Nelson Publishers.

. Bohrer, S.P. and Susanne Wenger, A. (1976). “Gods and Myths in Susanne Wenger’s Art: The Example of a Batik Cloth”. Nigeria Magazine, 120 (1976):12.

Greenblatt, S. (1992). The forms of power and the power of forms in the

renaissance. Genre, 15, 1-6.

Fo̩lo̩runs̩o̩, A.O. (1982). Àyè̩wò Ewì Àbáláyé, M.A. Dissertation, Ile-ife̩: University of

Ife̩. Ikudaisi, O. (1980). Òwe Yorùbá. Yorùbá Gbode, No 5, 27-31.

O̩de̩jo̩bi, C.O. (2001). Ìlò ohun àbáláyé nínú fíìmù àgbéléwò Yorùbá “Ègún Àìmò̩”láti

o̩wó̩ So̩la Mike Agboo̩la. In Yorùbá A journal of the Yoruba Studies Association

of Nigeria, 2 (1), 90-101.

Ogundeji, P.A. (1992). O literature in Yorùbá novels. African Notes: Journal of the

Institute of African Studies, University of Ibadan, xvi (1 & 2),23-31.

Ogunniran, L. (1992). O̩mo̩ Aláte̩ Ìlè̩kè̩. Ibadan: Lolyem Communication.

Ògúnṣínà, B. (1987). The sociology of the Yorùbá novel: A study of Isaac

Thomas, D.O. Fágúnwà and Ọládẹ̀jọ Òkédìjí. Unpublished Ph.D.,

Ìbàdàn: University of Ìbàdàn.

Ògúnṣínà, B. (1992). The development of the Yorùbá novel (1930-1975).

Ìbàdàn: Gospel Faith Mission.

Ọlábímtán, A. (1975). Religion as a theme in Fágúnwà Novels. Odu 11, pp.

-310.

O̩labimtan, A. (1980). Ètò àti ìlànà è̩kó̩ ewì Yorùbá ni ilé-ìwé giram àti ti è̩kó̩s̩é̩ olùkó̩.

Yorùbá Gbòde, No 5, 98-106.

Olajubu, O. (1978). Oríkì. Yorùbá Gbòde, 2 (3),15-27.

Ojaide, T. and T.M. Sallah (eds). (1999). The new African poetry: An anthology.

London: Lynne Rienner.

Okpewho, I. (1992). African oral literature: Backgrounds, characters, and continuity.

Bloomington: Indiana University Press.

Olate̩ju, A. (1999). The language of Yorùbá drama: Adebayo Faleti’s Baso̩run Gaa as

a case study. In papers in honour of Prof. Adelugba at 60, edited by Egbe Ifie,

-293.

Raji, S.M. (1991). Ìjìnlè̩ o̩fò̩, ògèdè àti àásán. Ibadan: Onibo̩noje Press and Book

Industries (Nig) Ltd.

Publicado

06-08-2025

Cómo citar

ADÉYE̩MÍ Ò̩jò̩gbó̩n O. . (2025). Ewì Alohùn Nínú Lítírés̩ò̩ Àpilè̩ko̩ Yorùbá: Ìwé Eré-onítàn O̩mo̩ Aláte̩ Ìlè̩kè̩ tí Láwuyì Ògúnniran ko̩ bí Àpe̩e̩re̩: Poemas na literatura iorubá: A história do filho do profeta, de Lawuyì Ógúnnirán. NJINGA&SEPÉ: evista nternacional e ulturas, Línguas fricanas rasileiras, 5(Especial I), 11–31. ecuperado a partir de https://revistas.unilab.edu.br/njingaesape/article/view/2322