Kọ́lá Owólabí: Akọni Akọ́mọlédè àti Ajàfẹ́tọ̀ọ́ Èdè Yorùbá
Kola Owolabi: um herói literário e um campeão da língua iorubá
Keywords:
Akitiyan Ọ̀jọ̀gbọ́n Kọ́lá Owólabí, Balógun ajàjà-gba-ra, ilé iṣẹ́ fún Ìṣàmúlò Èdè Yorùbá, ìṣelọ́jò, ìgbéga àti ìdàgbàsókè YorùbáAbstract
Ìwé àpilẹ̀kọ́ yìí ṣe àgbéyẹ̀wò ipa àti akitiyan Ọ̀jọ̀gbọ́n Kọ́lá Owólabí gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ìmọ̀ ẹ̀dá aláìlẹ́gbẹ́, àti Balógun ajàjàgbara fún ìṣelọ́jọ̀, ìgbéga, ìpolongo àti ìgbélékè èdè àti àṣà Yorùbá. Ìdí abájọ fún àyẹ̀wò àwọn ipa tí wọ́n kó wọ̀nyìí ni láti mọ̀ bóyá wọ́n dáńgájíá tàbí gbé ìwọ̀n gẹ́gẹ́ bí akọni pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ tíọ́rì oníbejì tí í ṣe: adènà-lílo-èdè-àjòjì àti ìró-èdè abínibí-lágbára tí Fishman ṣe agbátẹrù rẹ̀, a ṣe àfihàn iṣẹ́ takuntakun tí Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ṣe bí: olùkọ́ tí ó tayọ nínú fífi ìjìnlẹ̀ ìmọ̀ ẹ̀dá èdè ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn àdììtú nínú ìmọ̀ Yorùbá; jíjẹ́ Olùdarí àti Aláàkóso “Ilé Iṣẹ́ Èdè Yorùbá”; jíjẹ́ Olùdásílẹ̀ àti Gíwá “Ilé Iṣẹ́ fún Ìṣàmúlò Èdè Yorùbá”; jíjẹ́ agbátẹrù àpérò àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àgbáyé lórí lílo àwọn ọ̀nà-ìkọ́ni ìgbàlódé fún kíkọ́ Yorùbá; ṣíṣe ìwádìí lórí àwọn okùnfà ikú èdè àti ọ̀nà láti dènà rẹ̀ fún èdè Yorùbá; jíjẹ́ aṣáájú nínú ogun ìṣàmúlò èdè níbi gbogbo àti nígbà gbogbo; jíjẹ́ atúmọ̀ òfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti ìwé ìrìnnà láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí Yorùbá; kíké gbàjarè fún ìṣàmúlò èdè Yorùbá ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, ní ibiṣẹ́ ọba abbl; lílo ìkànnì ìtàkùn àgbáyé fún ìlanilọ́yẹ àti ìkọ́ni ní ẹ̀kọ́ Yorùbá; ṣíṣe àmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ fún ìpolongo Yorùbá. Ní àfikún, àwọn èèkan pàtàkì-pàtàkì ní àwùjọ, àwọn àjọ, aláṣẹ ilé iṣẹ́, ilé ìwé àti ilé iṣẹ́ ìròyìn ti gbé òṣùbà bàǹbà fún Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí. Àwọn àbálọbábọ̀ wa fún gbogbo akitiyan wọ̀nyìí fi hàn pé Kọ́lá Owólabí jẹ́ akọni tí ó la ipa rere mánigbàgbé fún ìṣelọ́jọ̀, ìgbéga àti ìdàgbàsókè Yorùbá.
******
Este artigo examina o papel e os esforços do Professor Kola Owolabi como um professor de ciências naturais de destaque e um defensor da promoção, disseminação e avanço da língua e da cultura iorubá. O objetivo de analisar essas contribuições é avaliar sua relevância e seu caráter heroico à luz de duas teorias propostas por Fishman: a barreira da língua estrangeira e a força da língua materna. Destacamos o trabalho árduo realizado por este professor, que inclui: atuação como professor excepcional, utilizando seu profundo conhecimento linguístico para analisar as nuances do saber iorubá; atuação como diretor e administrador do "Instituto da Língua Iorubá" (do qual também foi fundador); defesa global do uso de métodos modernos de ensino da língua iorubá; realização de pesquisas sobre as causas da extinção linguística e formas de preveni-la no contexto da língua iorubá; liderança na defesa do uso da língua em todos os âmbitos e momentos; tradução de leis e passaportes nigerianos do inglês para o iorubá; defesa do uso da língua iorubá no parlamento, em cortes reais, etc.; utilização da internet para a defesa e o ensino da língua iorubá; e uso de tecnologias de comunicação para a promoção do iorubá. Além disso, figuras de destaque da sociedade, organizações, líderes empresariais, escolas e a mídia prestaram homenagens ao professor. O reconhecimento de todos esses esforços demonstra que Kola Owolabi é uma figura heroica que causou um impacto positivo e inesquecível na sociedade, bem como na promoção e no desenvolvimento do povo iorubá.
Downloads
References
Amfani, A.H. (1997). Aspect of Agreement Relation in Hausas Clause Structure, An Unpublished PhD Thesis, University of Ìbàdàn, Ìbàdàn.
Bámgbóṣé, A. (1991). Language and the nation: The language question in Sub-Saharan Africa. Edinburg University Press.
Fishman, J.A. (1991). Reversing language shift: Theoretical and empirical foundations of assistance to threatened languages. Multilingual Matters.
Fishman, J.A. (2001). Can threatened languages be saved? Reversing language shift, revisited: A 21st century perspective. Multilingual Matters.
Owólabí, K. (1989, Àtúntẹ̀…). Ìjìnlẹ̀ Ìtúpalẹ̀ Èdè Yorùbá (Vol. 1): Fònẹ́tíìkì àti Fonọ́lọ́jì. Ìbàdàn: Oníbọnòjé Press & Book Industries (Nig.) Ltd.
Owólabí, K. (2007). Ó tó gẹ́ẹ́, ọmọ Odùduwà: Ogun Ìṣàmúlò èdè Yorùbá ní ibikíbi, ní ipòkípò àti ní àyèkáyè di jíjà wàyí.
PMParrot (2023, January 26). Out of about 50 million Yorùbá youths, only 650 interested in the language – Prof Kọ́la Owólabí.
UNESCO (2003). Education in a Multilingual World. Paris: UNESCO.
University of Ìbàdàn (2013). Teaching Yorùbá as a second foreign language: One-week international workshop report. University of Ìbàdàn, Yorùbá Language Centre.
Downloads
Published
How to Cite
Issue
Section
License
Copyright (c) 2026 NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial-NoDerivatives 4.0 International License.
Authors who publish in this journal agree to the following terms:
Authors maintain copyright and grant the journal the right to first publication, the work being simultaneously licensed under the Creative Commons Attribution License, which allows the sharing of the work with recognition of the authorship of the work and initial publication in this magazine.
Authors are authorized to assume additional contracts separately, for non-exclusive distribution of the version of the work published in this journal (eg, publishing in institutional repository or as a book chapter), with acknowledgment of authorship and initial publication in this journal.
Authors are permitted and encouraged to publish and distribute their work online (eg in institutional repositories or on their personal page) at any point before or during the editorial process, as this can generate productive changes, as well as increase impact and citation of the published work (See The Effect of Open Access).