Àfihàn ẹwúrù gẹ́gẹ́ bi akọnibìnrin ìlú mòro: ẹ̀rí láti inú lítíréṣọ̀ alohùn yorùbá
A representação de Ewuru como heroína da cidade de Mòrò: evidências da literatura popular ioruba
Keywords:
Òrìṣà Ewúrù, Akọnibìnrin, Lítírẹ́ṣọ̀ Alohùn, Tíọ́rì Àbùdá-Akọni, Ìlú MòroAbstract
Iṣẹ́ ìwádìí yìí ṣe àgbéyẹ̀wò àfihàn Ewúrù gẹ́gẹ́ bí akọnibìnrin nípasẹ̀ lítírẹ́ṣọ̀ àlọ́hùn Yorùbá. Àkíyèsí fi hàn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìwádìí tí ó ti wà lórí lítíréṣọ̀ alọ́hùn Yorùbá ni ó rọ̀ mọ́ akọni ọkùnrin, èyí tí ó mú kí ojúṣe àti agbára àwọn akọni obìnrin nínú ìtàn ìwáṣẹ̀ dín kù. Àfojúsùn wádìí yìí ni láti dí àlàfo yìí nípa ṣíṣe àyẹ̀wò Òrìṣà Ẹwúrù gẹ́gẹ́ bí akọnibìnrin ní ìlú Mòro láti túbọ̀ wo ipò akọnibìnrin nínú ìtàn àti àṣà Yorùbá. Ìlànà ìṣẹ̀wádìí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a lò fún iṣẹ́ yìí: àkọ́kọ́ ni ṣíṣe àkójọpọ̀ ewì Òrìṣà Ewúrù tí ó tọ́ka sí ìwà akọnibìnrin tí Ewúrù hù, èyí tí ó fi di akọni òrìṣà nígbà tí ó kú tán. Bákan náà ni a tún ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún àwọn agbátẹrù Òrìṣà Ewúrù (ọkùnrin àti obìnrin mẹ́sàn-án) ní ìlú Mòro. Ìlànà ìṣẹ̀wádìí kejì tí a lò ni ṣíṣe àmúlò àwọn ìwé tí ó wúlò fún iṣẹ́ yìí; bíi àwọn àpilẹ̀kọ, ìwé, àti àwọn ìwé orí ẹ̀rọ ayélujára. Ìtúpalẹ̀ àwọn àkójọpọ̀ wọ̀nyí ni a ṣe pẹ̀lú Tíọ́rì Àbùdá-Akọni (Archetypal Criticism). Àbájáde ìwádìí yìí fi hàn pé Ewúrù kì í ṣe òrìṣà lásán, bí kò ṣe akọnibìnrin tí ó lo agbára àbínibí àti ti ẹ̀mí rẹ̀ láti pèsè ààbò, àlàáfíà, àti ọmọ fún àwùjọ Mòro nínú ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Láòbú nígbà ayé wọn. Iṣẹ́ yìí fi kún ìmọ̀ nínú lítírẹ́ṣọ̀ àlọ́hùn Yorùbá nípa títọ́ka sí bí obìnrin ṣe ń jẹ́ òpómúléró ìdàgbàsókè àti ìṣọ̀kan nínú ìtàn ìwásẹ̀ ilẹ̀ Adúláwọ̀.
******
Esta pesquisa examina a representação de Ewuru como heroína na literatura oral iorubá. Vale ressaltar que a maior parte das pesquisas sobre a literatura oral iorubá tem se concentrado em heróis masculinos, o que acabou por diminuir o papel e o poder das heroínas na história e na narrativa. O objetivo deste estudo é preencher essa lacuna analisando a Deusa Ewuru como heroína na cidade de Mòro, a fim de aprofundar a compreensão sobre o papel da heroína na história e na cultura iorubá. Dois métodos de pesquisa distintos foram empregados neste trabalho: o primeiro consistiu em reunir poemas sobre a Deusa Ewuru que descrevem os feitos heroicos realizados por ela — ações que a elevaram ao status de deusa heroína após sua morte. Paralelamente, foram realizadas entrevistas com devotos da Deusa Ewuru (nove homens e nove mulheres) na cidade de Mòro. A segunda estratégia de pesquisa envolveu a utilização de literatura pertinente ao tema, incluindo artigos, livros e recursos online. A análise desse material foi realizada à luz da Crítica Arquetípica. Os resultados da pesquisa revelam que Ewuru não é apenas uma deusa, mas uma heroína que empregou seus poderes naturais e espirituais para proporcionar proteção, paz e descendência à comunidade de Mòro, no contexto de sua relação com Laobú àquela época. Este trabalho contribui para o conhecimento da literatura oral iorubá ao destacar o papel das mulheres como força motriz do desenvolvimento e da unidade na história do continente africano.
Downloads
References
Adéoyè, C. L. (1985). Ìgbàgbọ́ àti ẹ̀sìn Yorùbá. Evans Brothers Nigeria Publishers Limited.
Campbell, J. (1949). The hero with a thousand faces. Pantheon Books.
Deyab, M. C. (2023). Womanism, definition and history [Manuscript submitted for publication]. Department of English, Faculty of Arts, Minia University.
Fátùrótì, O. R. (2019). Ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá nínú Olódùmarè àti ìṣẹ̀dá ènìyàn. Nínú R. Adéṣuyan, S. M. Rájí, M. A. Fasehun, & I. F. Òjó (ol.), Ẹ̀kọ́ èdè, àṣà àti lítíréṣọ̀ Yorùbá (ojú-ìwé 148-169). Masterprint Publishers.
Faturoti, O. R. (2019). Litireso alohun ati esin ibile: Itupale ipo awon orisa ninu asa Yorùbá. Osun Journal of Yorùbá Studies, 4(2), 25–38.
Frye, N. (1957). Anatomy of criticism: Four essays. Princeton University Press.
Guerin, W. L., Labor, E., Morgan, L., Reesman, J. C., & Willingham, J. R. (2005). A handbook of critical approaches to literature (5th ed.). Oxford University Press.
Mbiti, J. S. (1990). African religions & philosophy (2nd ed.). Heinemann.
Ọládélé, B. (1986). Àwọn oríkì orílẹ̀ Mòro [Àpilẹ̀kọ fún gbígba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́]. University of Ilorin.
Reeve, C. (1990). The complete Tutenkhanmun: The king,the tomb, the royal treasure. Random House.
Downloads
Published
How to Cite
Issue
Section
License
Copyright (c) 2026 NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial-NoDerivatives 4.0 International License.
Authors who publish in this journal agree to the following terms:
Authors maintain copyright and grant the journal the right to first publication, the work being simultaneously licensed under the Creative Commons Attribution License, which allows the sharing of the work with recognition of the authorship of the work and initial publication in this magazine.
Authors are authorized to assume additional contracts separately, for non-exclusive distribution of the version of the work published in this journal (eg, publishing in institutional repository or as a book chapter), with acknowledgment of authorship and initial publication in this journal.
Authors are permitted and encouraged to publish and distribute their work online (eg in institutional repositories or on their personal page) at any point before or during the editorial process, as this can generate productive changes, as well as increase impact and citation of the published work (See The Effect of Open Access).