Òwe Yorùbá Gẹ́gẹ́ bí Àpẹẹrẹ Ọnà-èdè Alátinúdá Ajẹmẹ́wà: Kò Gbọdọ̀ Kú

Provérbios iorubás como exemplo de linguagem criativa: ela não deve morrer

Authors

Keywords:

Òwe, Ède, Ọnà-èdè, Ajẹmẹ́wà Alátinúdá, ]

Abstract

Iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ṣe àgbéyẹ̀wò òwe èdè Yorùbá tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ ilé àti ìpẹ̀tùsááwọ̀ láwùjọ Yorùbá. Yorùbá gbà pé òwe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọnà-èdè ajẹmẹ́wà alátinúdá èyí tó jẹ́ orísun ìmọ̀ ẹ̀kọ́-ilé àti ìpẹ̀tùsááwọ̀. Èdè Yorùbá jẹ́ ọ̀kan lára èdè abínibí ní Nàìjíríà tí ó ní olùsọ mílíọ̀nù ọgbọ̀n. Wọ́n tún ń sọ ọ́ ní Benin, Togo, Siera-Leone, Brazil, Cuba, Trinidad àti Tobago, Amẹ́ríkà abbl. Ó jẹ́ èdè olóhùn tó ní ìhun Olùwà-Ọ̀rọ̀-ìṣe-Àbọ̀ (Subject-Verb-Object). Ó jẹ́ ẹ̀yà ìpín èdè Benue Congo titun. Àmúlò òwe láwùjọ lóde òní kò dàbí ti àtijọ́ mọ́. Àwọn àgbàlagbà tí wọ́n máa ń pa òwe nípasẹ̀ ìrírí wọn ti ń dínkù. Àwa ọ̀dọ́ tí a sì wà kò ní ìrírí tó jinlẹ̀ tí ó sì lè mú kí a máa pa òwe láwùjọ. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò nípa ìmọ̀ wọn nínú òwe pípa ní pàtàkì èyí tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́-ilé àti ìpẹ̀tùsááwọ̀ ni wọ́n kùnà. Ìpèníjà lèyí, tó ń wá àmójútó ní kíákíá. Ìdí nìyí tí a fi dáwọ́ lé iṣẹ́ ìwádìí yìí, kí á lè wá ojútùú sí ìṣòro yìí, kí àwọn òwe wa má ba kú. Tíọ́rì ìbára-ẹni-gbé-pọ̀-láwùjọ àti ti ìpẹ̀tùsááwọ̀ ni a mú lò nínú iṣẹ́ yìí. Ọgbọ́n ìwádìí tí a mú lò fún àkójọpọ̀ èdè fáyẹ̀wò ni títọ àwọn olùsọ èdè yìí tí ọjọ́ orí wọn bẹ̀rẹ̀ láti àádọ́ta sí ọgọ́rin lọ fún oríṣiríṣi òwe àti àmúlò wọn. A wo àwọn ìwé àti iṣẹ́ àpilẹ̀kọ lórí òwe wò. A wo orí ẹ̀rọ ayélujára bákan náà. Àbájáde iṣẹ́ yìí jẹ́ ká ní ìmọ̀ nípa oríṣiríṣi àwọn òwe Yorùbá bó ti ṣe kan ẹ̀kọ́-ilé àti ìpẹ̀tùsááwọ̀. Ó wúlò fún kíkọ́ ọmọ ní ìwà ọmọlúwàbí èyí tó máa ń ṣe ìgbélárugẹ àṣà, ìṣe àti ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá, tó sì ń yọrí sí ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ alálàáfíà. Nínú iṣẹ́ yìí, a wo oríkì, ẹ̀dá káríayé àti ìwúlò òwe ní pàtàkì òwe fún ẹ̀kọ́-ilé àti ti ìpẹ̀tùsááwọ̀. A wo “Yorùbá” gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ àti àwọn ẹ̀yà kan. Òwe mú kí àyípadà dé bá àwùjọ sí rere. Ipa tó ń kó nínú ìpẹ̀tùsááwọ̀ láwùjọ kò kéré. Àwọn ìwúlò wọ̀nyí ni òwe kò fi gbọ́dọ̀ kú.

*******

Este artigo examina os provérbios iorubás relacionados à educação doméstica e à reconciliação na sociedade iorubá. Os iorubás acreditam que os provérbios são uma das artes da linguagem criativa, fonte de conhecimento sobre educação doméstica e reconciliação. O iorubá é uma das línguas indígenas da Nigéria, com trinta milhões de falantes. Também é falado no Benim, Togo, Serra Leoa, Brasil, Cuba, Trinidad e Tobago, Estados Unidos, etc. É uma língua tonal com estrutura sujeito-verbo-objeto. É um novo dialeto benue-congo. O uso de provérbios na sociedade atual não é o mesmo do passado. O número de adultos que usam provérbios com base em suas experiências está diminuindo. Nós, jovens, não temos a experiência profunda que nos leva a usar provérbios na sociedade. Muitos jovens que entrevistamos sobre seu conhecimento de provérbios, especialmente aqueles relacionados à educação doméstica e ao perdão, fracassaram. Este é um desafio que precisa de atenção urgente. É por isso que empreendemos este projeto de pesquisa, para encontrar uma solução para este problema, para que nossos provérbios não morram. A teoria da interação social e do perdão foi utilizada neste trabalho. O método de pesquisa utilizado para a coleta de dados foi entrevistar falantes dessa língua, com idades entre cinquenta e oitenta anos, para vários provérbios e seus usos. Analisamos livros e artigos sobre provérbios. Também consultamos a internet. Os resultados deste trabalho nos deram conhecimento sobre vários provérbios iorubás relacionados à educação doméstica e à reconciliação. Eles são úteis para ensinar às crianças boas maneiras que promovem a cultura, os costumes e as crenças iorubás, e levam à coexistência pacífica. Neste trabalho, examinamos a poesia, o mundo e os usos dos provérbios, especialmente aqueles para a educação doméstica e a reconciliação. O "iorubá" é visto como um meio de comunicação e um meio de comunicação entre certas tribos. Os provérbios trazem mudanças positivas na sociedade. Seu papel na reconciliação social não é pequeno. Esses são os usos que os provérbios não devem ser esquecidos.

Downloads

Download data is not yet available.

Author Biography

Raphael Ayodeji ADESUYAN, Adéyẹmí Federal University of Education, Oǹdó, Oǹdó State, Nigeria

Adeyemi Federal University of Education, Ondo, Nigeria: Akure, Ondo State, NG.

References

Adébọ̀wálé, O. àti D. Adélékè (2021). Àkọ̀tun Èdè Ìperí Yorùbá (New Yorùbá

Metalanguage). Ìbàdàn: Graceville Publishers.

Adéjùmọ̀, O. (2008). Issues in Yorùbá Contemporary Proverbs. Ìbàdàn: Al-Rabib Press

Ltd.

Adéṣuyan, R.A. (2010). “Àgbéyẹ̀wò Òwe Ìpẹ̀tùsááwọ̀ Láwùjọ Yorùbá”, nínú Ẹ̀GIN (Jọ́nà

Iṣẹ́ Akadá Ní Èdè Yorùbá), Department of Yorùbá, Adéyẹmí College of Education,

Oǹdó, Nọmba 1, o.i. 52-60.

Adéṣuyan, R.A. (2024). “Ipa Èdè Yorùbá Nínú Àyípadà Àwùjọ”, a paper presented at the

th National Conference of Yorùbá Language Scholars (ASSYLAS), 2024, held at the Federal College of Education (Special), Ọ̀yọ́, Ọ̀yọ́ State between Monday 8th – Friday, 12th July, 2024.

Adéyẹmí, S. (2006). Tíọ́rì Lítíréṣọ̀ ní èdè Yorùbá. Ìjẹ̀bú-Òde: Shebiotimo Publications.

Ajéwọlé, S. (2009). Ẹgbẹ̀ta Òwe Yorùbá àti Ìtumọ̀ Wọn. Àkúrẹ́: Almond-Ak Press Nig. Ltd.

Ajíbọ́lá, J.O. (1971). Òwe Yorùbá Pẹ̀lú Ìtumọ̀ sí Èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ìbàdàn: Oxford University

Press.

Awóbùlúyì, O. (1990). Yorùbá Metalanguage (Èdè-Ìperí Yorùbá) II. Ìbàdàn: University

Press Limited.

Awóbùlúyì, O. (2014). “Yorùbá Must Not Die Out”, Faculty of Arts Lecture, Faculty of Arts,

Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University, Ilé-Ifẹ̀, 6th February, 2014.

Badà, S.O. (1970). Òwe Yorùbá àti Ìṣẹ̀dálẹ̀ Wọn. Ìbàdàn: Oxford University Press.

Bámgbóṣé, A. (1968). “The Form of Yorùbá Proverbs”, nínú Odù Journal of African

Studies, Vol. 4, Nọ 2, o.i. 20-26

Bámgbóṣé, A. (1992). Yorùbá Metalanguage (Èdè-Ìperí Yorùbá) I. Ìbàdàn: University

Press Limited.

Délànọ̀, I.O. (1966). Òwe Lẹṣin Ọ̀rọ̀. Ìbàdàn: Oxford University Press.

Délànọ̀, I.O. (1973). “Proverbs, Songs and Poems” in Bíòbákú, S.O. (ed) Sources of

Yorùbá History. London: Oxford University Press.

Fájẹ́nyọ̀, S.O. àti Adéyẹyè, (2016). “Ipa Òwe Nínú Ìfẹsẹ̀múlẹ̀ Ìwà Ọmọlúwàbí Láwùjọ

Yorùbá Nínú Ìrìnàjò Ọgọ́rùn-ún Ọdún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà”, nínú Ìtànṣán Oòduà (Jọ́nà

Ẹgbẹ́ Olùkọ́ Èdè Yorùbá), Fọ́lúùmù Karùn-ún, o.i. 1-6.

Fásànyà, C.O. (1962). Àkójọpọ̀ Àwọn Òwe Yorùbá. Iléṣà: Olúṣẹ́gun Press.

Fátùrótì, O.R. (2022). “Àwọn Àyípadà tó dé bá Àgbékalẹ̀ àti Ìṣàmúlò Òwe Yorùbá” nínú

Adéjùbẹ́ẹ̀, S. àti I.F. Òjó (ed) Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Ìwòyí àti Ìpèníjà Lórí Èdè, Lítíréṣọ̀ àti Àṣà Yorùbá

(Contemporary Issues and Challenges in Yorùbá Language, Literature and Culture)

Festschrift in Honour of Dr. (Alhaji) Sulaymon Mohammed RÁJÍ, o.i. 249-261.

Federal Republic of Nigeria (2016). 2016 Population Census, Official Gazette,

(FGP71/52007/2, 500 (OL24).

Finnegan, R. (1970). Oral Literature in Africa. Oxford: Clarendon Press.

Friedman, Philip (2004). The New Websters Dictionary of the English Language

(International Edition). U.S.A: Lexcon Publication; Inc.

Greenberg, J.H. (1963). Language of Africa. The Hague: Mounton and Co.

Hymes, S. (1974). Foundations in Sociolinguistics: An Ethnographic Approach.

Philadephia: University of Pennsylvania Press.

Johnson, S. (1921). The History of the Yorubas. Lagos: C.M.S. Bookshops.

Ọlátúnjí, O. (1984). Features of Yorùbá Oral Poetry. Ìbàdàn: University Press Limited.

Òjóadé, O. (1985). “Africa Traditional Ethical Education and National Discipline: Proverbial

Evidence” nínú Folklore and National Development: A Seminar Proceedings, Ife,

Nigeria Folklore Society.

Taine, H. (1963-1993). History of English Literature.

Tubi, A. (1955). Ìwé Òwe ní Èdè Yorùbá. Yaba: Tubi Publishers.

Published

06-08-2025

How to Cite

ADESUYAN, R. A. . (2025). Òwe Yorùbá Gẹ́gẹ́ bí Àpẹẹrẹ Ọnà-èdè Alátinúdá Ajẹmẹ́wà: Kò Gbọdọ̀ Kú: Provérbios iorubás como exemplo de linguagem criativa: ela não deve morrer. NJINGA&SEPÉ: evista nternacional e ulturas, Línguas fricanas rasileiras, 5(Especial II), 171–178. etrieved from https://revistas.unilab.edu.br/njingaesape/article/view/2354