Ètò ìṣirò aládàdé-méjì àti àmúlùmọ́là odù ifá
O sistema numerológico e de dois dígitos do Rio Ifa
Abstract
ÀṢAMỌ̀
Ètò ìṣirò aládàdé-méjì, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú àgbékalẹ̀ Odù Ifá, ni a ó lò fi ṣàlàyé bí Odù
Ifá ṣe ń hù jáde lójú ọpọ́n nígbà ti a bá dá ifá kalẹ̀. A lo ìmọ̀ ìgbàlódé bí ó ṣe wà nínú ẹ̀kọ́ tó jẹ́ mọ́ àdàdé-méjì, ìyẹn akọ àti abo (+ àti -) tí wọ́n lo èdè kọ̀ǹpútà kọ bá yìí: ‘I’ ati ‘0’. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìmọ̀ ìgbàlódé tó jẹ́ mọ kọ̀ǹpútà ti ranirú àlàyé tí a lè ṣe nípa bí Odù Ifá ṣe ń hù. Àwọn baba mi ni ‘agbẹ́yìnkùlé-mọye-odù-tó-hù’. Inú kọ̀ǹpútà ló kù tí àwa yóò ti máa mọ Odù tó hù. A kò níí lo ‘II’ fún abo (-) nínú iṣẹ́ wa yìí ní ìbámu pẹ̀lú èdè tí kọ̀ǹpútà gbọ́. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀, abo mẹ́jọ àti akọ mẹ́jọ ló wà nínú ọ̀pẹ̀lẹ̀ àti àwọn ohun èlò mẹ́ta yòókù tí a lò fi ṣàlàyé Ifá dídá nínú iṣẹ́ yìí. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ẹ̀rù máa ń bà nígbà tí wọ́n bá rí ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni a ṣe lo obì àbàtà, owó-ẹyọ àti owó pa-unpa-un-ṣílè fi ṣe ìwádìí nǹkan lọ́wọ́ Ifá. Àjọṣepọ̀ tó wà láàrin akọ àti abo yìí ló bí gbogbo ọ̀tà- lérúgba-ó-dín-mẹ́rin (256) Odù Ifá nígbà tí a bá ṣe àmúlùmọ́là Odù méjì àkọ́kọ́ tí a gbà pé àwọn ló bí Odù yòókù. Ogbèyẹ̣̀kú ni baba àmúlù. Èyí ni wọ́n ń kọ ní ọlọ́kọ̀ gbọọrọ bá yìí ní èdè kọ̀ńpútà: 0101010101010101. Wọ́n sì le tò wọ́n wá sílẹ̀ ní olóòró (àtòwálẹ̀) bí a ṣe rí i nínú Odù Ifá (“Permutation,” 2021).
Downloads
Downloads
Published
How to Cite
Issue
Section
License
Copyright (c) 2025 NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial-NoDerivatives 4.0 International License.
Authors who publish in this journal agree to the following terms:
Authors maintain copyright and grant the journal the right to first publication, the work being simultaneously licensed under the Creative Commons Attribution License, which allows the sharing of the work with recognition of the authorship of the work and initial publication in this magazine.
Authors are authorized to assume additional contracts separately, for non-exclusive distribution of the version of the work published in this journal (eg, publishing in institutional repository or as a book chapter), with acknowledgment of authorship and initial publication in this journal.
Authors are permitted and encouraged to publish and distribute their work online (eg in institutional repositories or on their personal page) at any point before or during the editorial process, as this can generate productive changes, as well as increase impact and citation of the published work (See The Effect of Open Access).