Orin dàdàkúàdà gẹ́gẹ́ bí atọ́nà ìgbáyégbádùn láwùjọ
A música como guia para a felicidade social
Keywords:
Dàdàkúàdà, Ìgbáyégbádùn, Ọ̀rínkínniwín, ÀwogbèAbstract
ÀSAMỌ̀
Kókó pàtàkì tí iṣẹ́ yìí dá lé lórí ni àgbéyẹ̀wò ìwúlò orin dàdàkúàdà tó jẹ́ ọ̀kan lára orin ìbílẹ̀ Yorùbá ní Ìlọrin gẹ́gẹ́ bí atọ́ka ìgbáyégbádùn, ìwà ọmọlúàbí àti ìbágbépọ̀ àlàáfíà láwùjọ wa. Nítorí pé iṣẹ́ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ tí àwọn olùwádìí kọ lédè Yorùbá nípa orin dàdàkúàdà Ìlọrin, ìdí nìyí tí a fi kọ àpilẹ̀kọ yìí lédè abínibí láti lè ṣe òrínkíniwín àlàyé nípa orin ìbílẹ̀ Ìlọrin náà tí ẹ̀dọ̀ki èdè kúnnú rẹ̀ fọ́fọ́ọ́fọ́ gẹ́gẹ́ bí àfikún ìmọ̀. Iṣẹ́ yìí ṣàfihàn ìwúlò orin lápapọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ tí a ń fi orin jẹ́ láwùjọ ọmọ ènìyàn. Ó sì ṣe àgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àkóónú orin dàdàkúàdà lára àwọn òjìnmí elérée dàdàkúàdà nílẹ̀ Ìlọrin bíi Jáígbadé Àlàó, Odòlayé Àrẹ̀mú, Ọmọékeé Àmọ̀ó àti Àrẹ̀mú Òsé gẹ́gẹ́ bí àwògbè. Àwọn olórin ti a yàn láàyò yìí ni ìpèdè Yorùbá wọn jinlẹ̀ nínú àwọn àwo orin wọn, tó sì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgbọ́n àti òye tí ènìyàn lè ṣàmúlò láti tún ọmọlúàbí rẹ̀ ṣe nípa ìhùwàsí tó lè ṣe okùnfà ìbágbépọ̀ àlàáfíà fún ìtẹ̀síwájú àwùjọ. Lóòótọ́ ni àwọn orin mìíràn wà tó jẹ́ ti ìbílẹ̀ Ìlọrin tí a mọ̀ wọ́n mọ̀ bí orin bàlúù, orin wákà, orin kèǹgbè, orin kàkàkí àti bẹ̀ǹbẹ́, orin ọlọ́mọ́-ọba, orin agbè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n láàrin obì, ọ̀tọ̀ làá yọ oófúà sí ni ọ̀rọ̀ orin dàdàkúàdà. Iṣẹ́ yìí wa ṣe àtúpalẹ̀ àwọn kókó díẹ̀ nínú àkóónú orin àwọn àṣàyàn olórin dàdàkúàdà náà. Tíọ́rì ìmọ̀-ìbárá-ẹni-gbé-pọ̀ ni a lò láti ṣe àtúpalẹ̀ àwọn kókó atáwùjọṣe tí a ṣàmúlò nínú àwọn orin náà, nítorí pé ìbágbépọ̀ ẹ̀dá wà lára kókó pàtàkì tó ń bí orin kíkọ nínú àwùjọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé ti di ayé ọ̀làjú báyìí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkọkúkọ orin ti gbòde kan, èyí ni ó fà á tí iṣẹ́ yìí fi ṣàfihàn orin dadakúàdà gẹ́gẹ́ bí ọ̀tọ̀lórìn tí gbígbọ́ rẹ̀ kún fún ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye èyí tó lè ṣàǹfààní fún wa nípa híhu ìwà ọmọlúàbí, ìgbáyégbádùn àti ìbágbépọ̀ àlááfíà, kí àwọn ènìyàn àwùjọ sì má baà gbàgbé ogún rere tó wà nílẹ̀ nínú orin àti àwọn ìpohùn ìbílẹ̀ wa gbogbo.
******
O foco principal deste trabalho é examinar o uso da música dadakuada, uma das canções tradicionais iorubás em Ilorin, como indicador de felicidade, civilidade e coexistência pacífica em nossa sociedade. Como não há muitos trabalhos escritos por pesquisadores na língua iorubá sobre a música dadakuada em Ilorin, este artigo foi escrito na língua nativa, a fim de fornecer uma explicação detalhada da canção tradicional iorubá, tão rica em conhecimento, como complemento. Este trabalho demonstra o uso da música em geral por meio das diversas funções que ela desempenha na sociedade humana. Ele também revisou alguns dos conteúdos das canções de músicos famosos da terra de Ilorin, como Jáígbáde Áláo, Odòlayé Árému, Omoekeé Aboáo e Árému Ósé, como exemplos. Os músicos selecionados possuem uma profunda língua iorubá em suas canções, repletas de sabedoria e compreensão que podem ser usadas para reformar sua família por meio de um comportamento que leve à coexistência pacífica para o progresso da sociedade. Embora existam outras canções tradicionais de Ilorin, como balu, waka, kêngbe, kàkaki e benbe, lomômô-óba, agbé e outras, entre as obi, a mais proeminente é a música dadakúada. Este trabalho analisa alguns aspectos do conteúdo musical dos músicos dadakúada. A teoria da interação social é utilizada para analisar os elementos sociais presentes nas canções, visto que a interação social é um dos principais fatores que dão origem à música na sociedade. Embora o mundo tenha se tornado um mundo civilizado, onde muitos gêneros musicais se difundiram, é por isso que esta obra apresenta a música dadakūada como um gênero único, cuja audição é repleta de sabedoria, conhecimento e compreensão, que pode nos beneficiar ao promover a virtude cívica, a felicidade e a coexistência pacífica, para que as pessoas da comunidade não se esqueçam da boa herança que reside em nossa música e vozes tradicionais.
Downloads
References
Àwọn ìwé Ìtọ́kasí
Abímbọ́lá,W. (1975). Poetry in Music, Dance and Drama. Yorùbá Oral Traditions. Department of African Languages and Literatures. University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀. Ìbàdàn: University of Ìbàdàn Press.
Abímbọ́lá,W. (2006). Ìjìnlẹ̀ Ohùn Ẹnu Ifá, Apá kínní. Ìbàdàn: University Press Plc.
Adéọlá, T.S. (1997). “A Socio-Musical Study of Dadakúàdà in Ìlọrin, Kwara State, Nigeria”. M.A. Thesis, Department of Music. Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University, Ilé-Ifẹ̀.
Adéọlá, T.S. (1999). “The Historical Development of Dadakúàdà Music,” nínú Alore: Ìlọrin Journal of the Humanities” No. 1, vol. 1.
Adégbìtẹ́, A. (1999). “The Influence of Islam in Yorùbá Music”. Oríta Ìbàdàn Journal of Religious Studies. Vol. 16.
Agbájé, J.B. (1995). “A Literary Study of the Folksongs of Èkìtì People of Nigeria”. Ph.D Thesis, Department of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ìlọrin, Ìlọrin.
Ajíbádé, G.O. (2005). “Multifaces of Word in Yorùbá Orature.” Journal of Language and Literature, 4 (1), 20-39.
Ajíbóyè, O. (2003). Ewì Alohùn Yorùbá. Ìlọrin: Majab Books.
Àkàndé, F.O. (1994). “Orin Abíwẹ́rẹ́ fún àwọn Aláboyún àti Àwọn Oníbìísí ní Òde-Òní”. B.A. Long Essay, Department of African Language and Literature, Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University, Ilé-Ifẹ̀.
Akíwọwọ, A. (1986). “Àṣùwàdà Ènìyàn” in IFẸ̀: Annals of the Institute of Cultural Studies, University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀, Nigeria No. 1. pp. 113-123.
Barber, K. (1979). “Sociology of Literature”. Seminar paper, Department of African Languages and Literatures, University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀.
Beier, H.U., àti Gbàdàmọ́sí B. (1959). Yorùbá Poetry. Ìbàdàn: Government Printers.
Dáramọ́lá, O., àti Jéjé, A. (1967). Àwọn Àṣà àti Òrìṣà Ilẹ̀ Yorùbá. Ìbàdàn: Oníbọn-òjé Press.
Euba, A. (1975). “The Interrelationship of Music and Poetry in Yorùbá Tradition”. A seminar on Yorùbá Oral Tradition: Poetry in Music, Dance and Drama. University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀ pp. 470-489.
Ibekwe, E.U. (2014). The Role of Music and Musicians in Promoting Social Stability in the Country. UJAH Unizik Journal of Arts and Humanities. Vol 14 (3):159. DOI:10.4314/ujah. v14i3.10
Idolor, G.E. (n.d). Music in Contemporary African Society. Compilations of Some
Published Articles by Professor Idolor.https//:www.academia.edu/13628580/Compilation...
Ilésanmí, T.M. (1985). “Heartstones: A Cultural Study of Songs in Ijesaland,” Ph.d. Thesis, Department of Linguistics and African Languages, Ọbáfẹ́mi Awólawọ̀ University, Ilé-Ifẹ̀.
Laurenson D., and Swingwood, A. (1971). The Sociology of Literature. London: Mac Gibbon and Kee.
Na’Allah, A.R. (1992). Dadakúàdà: The Crisis of a Traditional Oral Genre in a Modern Islamic Setting”. Journal of a Religion in Africa. Vol. 22 Pp. 318-330.
Na’Allah, A.R. (1994). Dàdàkúàdà as one of the Oral Art forms of Ìlọrin, African Notes: Journal of the Institute of African Studies, University of Ìbàdàn, Ìbàdàn. Vol. 18. Nos. 1 & 2. Pp. 29-50.
Nketia, J.H. (1962). African Music in Ghana, Accra: Longman, Green and Co. Ltd.
Ògúnsínà, J.A. (1987). “The Sociology of the Yorùbá Novel”. Unpublished Ph.D. Thesis, University of Ìbàdàn, Ìbàdàn.
Ògúnpolú, F. (1975). “Ọ̀kọ̀sì Festival Songs”. Yorùbá Oral Tradition. Wándé Abímbọ́lá (ed.). Department of African Language and Literature, University of Ifẹ̀, Ilé-Ifẹ̀. o.i. 551-598.
Olúkòjú, E.O. (1985). “Some Features of Yorùbá Song”. West African Languages and Education, West African Linguistics Society. o.i. 37-43.
Olúkòjú, E.O. (1987). “Music in Religious Worship”, ORITA: A Journal of Religious Studies Association of Nigeria. University of Ìbàdàn, Ìbàdàn. o.i. 118.
Rájí, S.M. (1987). “Orin Ọ̀tẹ̀”. M.A. Thesis, Department of Languages and Literatures; Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ University, Ilé-Ifẹ̀.
Ìtàkùn Ayélujára
www.alaroyeonline.com/../2326.pdf
yo.wikipedia.org/wiki/ilọrin
Ìwé Àtìgbàdégbà
Aláròyé (2012). “Ìjà àwọn Yorùbá àti Fúlàní nítorí Ìlú Ìlọrin”. Vol. 37. No. 3, November 27. pp. 18-21.
Àwọn Olórin Dadakúàdà tí a lò fọ́nrán orin wọn
- Jáígbadé Àlàó
- Odòlayé Àrẹ̀mú
- Ọmeékeé Àmọ̀ó
- Àrẹ̀mú Òsé
- Kọ́lá Olóoru.
Downloads
Published
How to Cite
Issue
Section
License
Copyright (c) 2025 NJINGA&SEPÉ: Revista Internacional de Culturas, Línguas Africanas e Brasileiras

This work is licensed under a Creative Commons Attribution-NonCommercial-NoDerivatives 4.0 International License.
Authors who publish in this journal agree to the following terms:
Authors maintain copyright and grant the journal the right to first publication, the work being simultaneously licensed under the Creative Commons Attribution License, which allows the sharing of the work with recognition of the authorship of the work and initial publication in this magazine.
Authors are authorized to assume additional contracts separately, for non-exclusive distribution of the version of the work published in this journal (eg, publishing in institutional repository or as a book chapter), with acknowledgment of authorship and initial publication in this journal.
Authors are permitted and encouraged to publish and distribute their work online (eg in institutional repositories or on their personal page) at any point before or during the editorial process, as this can generate productive changes, as well as increase impact and citation of the published work (See The Effect of Open Access).