Ìṣàfihàn onírúurú ọ̀nà ìjóbìnrin nínú àṣàyàn iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ Yorùbá

Representations of women dynamism in selected Yorùbá literary genres

Authors

Keywords:

Literature, Woman, Gender

Abstract

ÀṢAMỌ̀

Ìmọ̀ nípa ìbáṣepọ̀ tó wa láàrin takọ-tabo ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ láàrin àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ lẹ́lẹ́kajẹ̀ka. Obìnrin àti ipò wọn gẹ́gẹ́ bí àṣà àti ìṣe ti fi lọ́lẹ̀ sì jẹ wọ́n lógún. Àwọn onímọ̀ kan gbà pé àṣà àwùjọ Yorùbá n gbé èrò akọ-lo-lórí lẹ́yìn àmọ́ ọ̀pọ̀ ìwádìí lo tún ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ipò àti ipa pàtàkì ni obìnrin ti kó, tí wọ́n sì tún ń kó láwùjọ Yorùbá. Àfojúsùn iṣẹ́  yìí ni ṣíṣe àyẹ̀wò ipò àti ipa tí obìnrin ń kó nínú ètò àti ẹ̀tọ́ ìlú bí ó ti hàn nínú àṣàyàn lítíréṣọ̀ Yorùbá. Tíọ́rì Ìṣẹ̀tófábo ti Clenora Hudson-Weems ni a gùnlé láti ṣàtúpalẹ̀ àṣàyàn oríkì orílẹ̀, eré-onítàn àti fíìmù Yorùbá tí a mọ̀-ọ́n-mọ̀ yàn láàyò nítorí àkóónú wọn. Àwọn iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ náà ni: Akínwùmí Ìṣọ̀lá, Ẹfúnṣetán Aníwúrà, Olú-Ọmọ, Ẹfúnróyè Tinúubú; Oríkì Arẹ̀sà bí ó ti hàn nínú Adébóyè Babalọlá Àwọn Oríkì orílẹ̀ Mẹ́tàdínlógún; àti fíìmù àgbéléwò Fúnmiláyọ̀ Ransome Kútì tí Túndé Babalọlá kọ.  Iṣẹ́ yìí fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ipa pàtàkì ni àwọn obìnrin ti ń kó láwùjọ Yorùbá láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. Bákan náà ó hàn pe ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ní àwọn obìnrin kan. Síwájú sí, ipa tí obìnrin ń kó nínú ètò àti ẹ̀tọ́ ìlú ní ayé àtijọ́ títí di òní kò ṣe é fọbẹ̀ bù dànù. Bákan náà ni iṣẹ́ yìí fi hàn wí pé láti ayébáyé ni àyè ti gba obìnrin ní àwùjọ Yorùbá. Iṣẹ́ yìí tún fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lítíréṣọ̀ Yorùbá jẹ́ ohun èlò láti fi ìjóbìnrin lọ́lẹ̀ láwùjọ. Ó sì tún fi hàn pé a le lò ó láti fi èrò báyéserí ẹni múlẹ̀.

******

Studies on gender discourse in African society has been privileged by scholars in almost all discipline. Existing studies in Yorùbá have focused largely on the cultural tradition and role of women. Generally, the Yorùbá people are assumed to be culturally patrilineal with women often subjugated and marginalized. This study, therefore, using Clenora Hudson-Weems African Womanism approach, this paper was designed to examine the dynamism of Yorùbá women as represented in selected Yorùbá literary genres, with a view to establishing the place of women in human, social and national development. The interpretive design was used to examine one Oríkì orílẹ̀, three plays and a home video purposively selected due to their thematic relevance. They are Akínwùmí Ìṣọ̀lá’s Ẹfúnsetán Aníwúra, Olú Ọmọ and Ẹfúnróyè Tinúubú; Oríkì Arẹ̀sà as documented in Adébóyè Babalọlá’s Àwọn Oríkì Mẹ́tàdínlógún and Túndé Babalọlá’s Fúnmiláyọ̀ Ransome Kútì. The texts were subjected to literary analysis. The study reveals that women occupy a significant space in both the pre-literate and contemporary era, with some women emerging as human rights activists and advocates. The paper establishes that Yorùbá literary genres have been used as weapons to negotiate spaces for women, and also as a tool used to herald the voice of women both in the pre-colonial and contemporary Yorùbá society and by extension, the larger Nigerian society.

Downloads

Download data is not yet available.

References

Ìwé ìtọ́kasí

Abimbola, W. (1968). Ìjìnlẹ̀ Ohun ẹnu Ifá – Apá kìíní. London: Collins.

Adejumo, A. (2017) Ïpo Wo Lobìnrin wà Nínú Ìtàn Àròsọ Fágúnwà”in Adélékè Adéẹ̀kọ́ and

Akin Adésọ̀kàn (eds). Celebrating Literary History: Ibadan: Bookcrafts.

Adejumo, A. (2022). Negotiating Cultural Dynamism: Woman and Gender Relation in the Novels of D.O. Fagunwa in Àkàngbé C.A, Orímóògùnjẹ́ O.C. & Falẹyẹ A.A. (Eds). New Trends in Yorùbá Language, Literature and Culture. Ibadan: Clemeve Media Konsult, Pp 144-166.

Adeleke, A. (2017) “Sex, Gender and Plot in Fagunwa’s Adventures” in Adeleke Adeeko and Akin Adesokan (eds). Celebrating D.O. Fagunwa Aspects of African and World Literary History. Ibadan: Bookcraft, 2017.

Awe, B. (1992). “ Iyalode Ẹfunṣetan Aníwura (Owner of Gold)”, in Bolanle Awe (ed). Lagos: Sankora Publishers.

Babalola, S. A. (2001). Àwọn Oríkì Mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n. Lagos: Longman Nigeria Plc.

Babalola, T. (2024). Funmilayo Ransome Kuti. Produced by BAP Productions, Lagos.

Bolarinwa, A. (2019). “Women in Adébáyọ̀ Fálétí’s Poetry”. Yorùbá Studies Review. Ibadan: Library Press OUF. Pp 135-150.

Denzer, L. (1994). Yorùbá Women: A Historiographical study. International Journal of African Historical Studies, vol. 27, pp 1-39.

Fadipe, N.A. (1970). The Sociology of the Yorùbá. Ibadan: University Press.

Hudson-Weems, C. (1994). Africana Womanism: Reclaiming Ourselves. Troy: Bedford Publishers.

Kolawole, M. (1997). Womanism and Africa Consciousness. Africa World Press. New Jersey.

Isola, A. (1983). Olú Ọmọ. Onibonoje Press and Book Industries (Nig.) Ltd.

Isola, A. (2009). Ẹfunroye Tinuubu. Ibadan: DB Martoy Books

Isola, A. (1970). Efunsetan Aniwura. Ibadan: University Press Plc.

Johnson, S. (1921). The History of the Yorùbás. Lagos: CSS Bookshops.

Nwajiaku, I. (2004). “Representations of Womanist Discourse in the Short Fiction of Akachi. Ezeigbo and Chinwe Okechuckwu. In New Women’s Writing in African Literature, volume 24, (Eds) E. Emenyonu. New Jersey: Africa World Press.

Ọmọtayọ, A.A. (2025). Representations of Sexual Orientation in Twenty-first Century African Prose Narratives. A Thesis in the Department of English, University of Ibadan.

Ọ̀pẹ́fèyítìmí, A. (2009). “Women of the World” in Yorùbá Culture. Women in Yorùbá Culture: A Dozen of Academic Articles Ibadan: Penthouse Publications., pp.121-133

Published

06-08-2025

How to Cite

ADÉJÙMỌ̀ A. G. . (2025). Ìṣàfihàn onírúurú ọ̀nà ìjóbìnrin nínú àṣàyàn iṣẹ́ ọnà aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ Yorùbá: Representations of women dynamism in selected Yorùbá literary genres. NJINGA&SEPÉ: evista nternacional e ulturas, Línguas fricanas rasileiras, 5(Especial I), 127–139. etrieved from https://revistas.unilab.edu.br/njingaesape/article/view/2328